Nitori owo ti wọn lo ko jẹ, awọn aṣofin Ọṣun fẹẹ gbena woju olori wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Dugbẹdugbẹ to n mi loke lọwọlọwọ bayii nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, bi wọn ko ba tete wa nnkan ṣe si i, afaimọ ki wọn ma yọ olori wọn nipo ko too di ipari saa rẹ loṣu Karun-un, ọdun yii.

Owo kan ti ahesọ sọ pe o jẹ ogoji miliọnu Naira, la gbọ pe Gomina Ademọla Adeleke fun olori ile, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, pe ko fi ṣọdun fawọn aṣofin to ku atawọn oṣiṣẹ ibẹ lasiko Keresimesi ati ọdun tuntun to kọja lọ.

Ṣugbọn bi ọrọ owo naa ko ṣe lakanti la gbọ pe o n bi gbogbo awọn aṣofin naa; ati ti ẹgbẹ APC ati ti ẹgbẹ PDP ninu bayii, wọn ni opin gbọdọ de ba bo ṣe maa n tẹ awọn loju mọlẹ.

Iwadii fi han pe ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa Naira (#250,000) ni Owoẹyẹ fun awọn aṣofin kọọkan, ti apapọ wọn si jẹ mẹrindinlọgbọn, eyi ti ko si tẹ wọn lọrun.

Koda, a gbọ pe awọn aṣofin ọhun lọọ ṣepade to gbona kan l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nile itura kan niluu Oṣogbo, nibi ti wọn ti ta ku pe ko si ofin to fun Owoẹyẹ lagbara lati maa gun awọn garagara.

Nigba ti aṣofin kan ti ko fẹ ka darukọ oun n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni iwa ti olori ile ọhun hu ko tẹ awọn lọrun rara.

O ni lootọ lawọn gbọ pe Owoẹyẹ lo lara owo naa lati fi ra irẹsi, ororo ati adiyẹ fun awọn oṣiṣẹ ileegbimọ aṣofin pẹlu awọn ti wọn maa n gbe nnkan fun lọdọọdun, sibẹ o yẹ ko maa fi gbogbo igbesẹ yii to awọn aṣofin to ku leti.

O ni awọn ṣi wa lori ọrọ naa, o si di dandan kawọn tuṣu desalẹ ikoko lati mọ igbesẹ to ku lati gbe.

Amọ ṣa, Agbẹnusọ funolori awọn aṣofin ọhun, Kunle Alabi, sọ pe ko si ede aiyede kankan laarin awọn aṣofin naa, owo ko si le da ija silẹ laelae nitori pẹlu iṣọkan ni wọn fi maa n ṣe gbogbo nnkan.

Leave a Reply