Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari bi ọwọngogo ounjẹ ṣe n gbilẹ si i kaakiri ipinlẹ Ondo, Gomina Rotimi Akeredolu ni oun ti fofin de ọkan-o-jọkan ẹlẹgbẹjẹgbẹ tawọn oniṣowo pẹlu awọn oniṣẹ-ọwọ ko jọ lati maa fi ni awọn araalu lara lorukọ ẹgbẹ ti wọn n ṣe.
Ikede ati ikilọ yii waye ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, fi sita lorukọ gomina lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Arakunrin ni abọ iwadii tijọba ṣe tí fidi rẹ mulẹ pe ẹlẹgbẹjẹgbẹ tawọn oniṣowo ọhun n ṣe ko ipa pataki lara ohun to n mu nnkan le koko fawọn araalu nipasẹ owo nla ti wọn n gba lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ ati bi wọn ṣe n fi dandan le iye ti wọn gbọdọ maa ta ọja fawọn araalu.
Gomina ni ko si aaye fun olori ẹgbẹ kan tabi awọn isọngbe rẹ rẹ lati ja tikẹẹti tabi gbowo kankan lọwọ ẹnikẹni lorukọ pe awọn n ṣẹgbẹ
Gbogbo awọn oniṣẹ-ọwọ, oniṣowo atawọn agbẹ lo ni oun ti fun laṣẹ lati lọọ maa ta ọja wọn niye to ba ti wu wọn lai si ẹni to gbọdọ yọ wọn lẹnu nitori pe ọkan pataki lara ojuṣe ijọba ni lati peṣe aabo atawọn nnkan amayedẹrun fawọn araalu.
Gomina Akeredolu ni Ọjọbọ, Tọsidee, gan-an laṣẹ tuntun naa gbọdọ bẹrẹ, ko si fẹsẹ mulẹ ni gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo.
O ni ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o tẹ ofin naa loju ko ni i sai jiya nla labẹ ofin.