Nitori owu jijẹ, Beatrice la igi mọ ọkọ rẹ lori l’Okitipupa, lo ba ku patapata

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Owu ajẹju ti mu ki iyawo ile kan, Oueen Beatrice, ran ọkọ rẹ, Emmanuel Ikujuni, lọrun ọsan gangan niluu Ọmọtọṣọ, nijọba ibilẹ Okitipupa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, obinrin ọmọ bibi ipinlẹ Delta ọhun ni wọn lo binu la apola igi nla kan mọ oloogbe lori latari ariyanjiyan kan to bẹ silẹ laarin wọn lori ẹsun agbere to fi kan ọkọ rẹ.

Obinrin kan ti ko sẹni to mọ bo ṣe jẹ si oloogbe ọhun ni wọn lo pe e sori ago lasiko ti oun ati iyawo rẹ jọ n jiroro lọwọ lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye.

Eyi lo bi iyawo rẹ ninu to fi gbe ija ko o loju, wọn lo fẹsun kan ọkọ rẹ pe o lori laya lati maa ba ale rẹ sọrọ niwaju oun.

Awọn eeyan kan to wa nitosi lasiko tiṣẹlẹ yii waye sare gbe ọkunrin naa lọ si ileewosan kan to wa nitosi, nibi tawọn dokita tí fidi rẹ mulẹ pe o ti ku.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe wọn ti fi to awọn ọlọpaa leti, bẹẹ ni wọn ti fi afurasi ọdaran naa ṣọwọ si ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran ni olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa l’Akurẹ.

Leave a Reply