Nitori owu jijẹ, Happiness la igi mọ iyawo ọkọ rẹ lori l’Akurẹ, niyẹn ba gba’bẹ ku

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ obinrin kan, Happiness Emmanuel, ẹni tí wọn fẹsun kan pe o ṣeku pa iyawo ọkọ rẹ, Napre Blessing Emmanuel, l’Akurẹ.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti ija kan pa awọn mejeeji pọ ninu ile ti wọn n gbe niluu Ọda, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni iṣẹlẹ naa waye.

Happiness ni wọn lo kọkọ binu la igi mọ obinrin naa lori ko too tun fi ọkọ ṣa a lori ati ni gbogbo ara, eyi to pada ja siku fun un.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni oku Blessing ṣi wa ni mọsuari ileewosan ijọba to wa l’Akurẹ, nibi ti wọn tọju rẹ pamọ si, ti iwadii si n tẹsiwaju lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan iyawo ile ọhun.

Leave a Reply