Nitori oye ọba awọn Hausa to fẹẹ fi jẹ niluu naa, Ọba Jẹbba wọ Emir Ilọrin lọ sile-ẹjọ 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọba ilu Jẹbba, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara, Abdulkadir Adebara, ati Serikin Hausawa tilu ọhun, Yusuf Gbadabe, ni wọn wọ Emir Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Zulu Gambari, lọ sile-ẹjọ pe ki wọn da a lọwọ kọ lati ma ṣe fi Nasir Iliyasu jẹ oye Serikin Hausawa ni ilu Jẹbba.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni wọn gbe ẹjọ lọ siwaju Onidaajọ E. B. Mohammed pe ki ile-ẹjọ pasẹ fun Emir Ilọrin pe ko gbọdọ fi Nasir Iliyasu jẹ oye Serikin Hausawa niluu Jẹbba. Adekunle Bamidele to gbe ẹjọ naa siwaju adajọ lorukọ ọba ilu ọhun ati Serikin Hausawa ọhun sọ pe lati ọdun 2017 ni Ọgbẹni Yusuf Gbadabe ti jẹ oye Serikin Hausawa ti gbogbo ilu mọ, to si jẹ pe Ọba Jẹbba, Kinrinjin Adebara ati alaga ijọba ibilẹ Moro to wa lori aleefa lọdun 2017 lo buwọ lu iyansipo rẹ nigba naa lọhun-un. Ṣugbọn ni bayii, Emir Ilọrin tun fẹẹ fi Nasir Iliyasu jẹ oye Serikin Hausawa miiran niluu Jẹbba, to si fẹẹ we lawani oye fun un niluu Ilọrin lọjọ keji, oṣu keje, ọdun yii. Wọn ni kile-ẹjọ jọwọ jare, ki wọn kilọ fun un, ko ma dan an wo.

Onidaajọ E. B. Mohammed wa sọ pe latari pe wọn ko tete fi orukọ ẹjọ naa silẹ, ti ko si si akoko pupọ mọ, oun sun igbẹjọ naa si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, ọdun yii.

 

Leave a Reply