Nitori pe Fayẹmi ti kọ iṣejọba silẹ, awọn ọdaran ti gba ipinlẹ Ekiti-PDP

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ oṣelu  People’s Democratic Party (PDP) nipinlẹ Ekiti ti fẹsun kan Gomina Kayọde Fayẹmi pe ko bikita nipa eto aabo mọ, bi yoo ṣe di aarẹ tabi igbakeji rẹ lọdun 2023 lo n ba kiri.

Eyi jẹ yọ ninu lẹta kan ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa l’Ekiti, Raphael Adeyanju, fọwọ si lọjọ Aje, Mọnde, niluu Ado-Ekiti.

Adeyanju ṣalaye pe bi awọn ajinigbe ṣe ji gbajugbaja oniṣowo epo kan, Alhaji Sulaiman Akinbami, gbe fi han pe awọn ọdaran naa ti wọ olu-ilu Ekiti, ko si sẹni ti aabo daju fun mọ.

Akọwe ipolongo naa ni pẹlu bi Alhaji Akinbami ṣe nawo to lati gbe Fayẹmi sori aleefa, gomina naa ko le daabo bo ẹmi ẹ, eyi si fi han pe ko sẹni ti wọn ko le ṣe nijamba l’Ekiti lasiko yii.

O ni, ‘‘Lasiko ọdun Keresi ni wọn ji Ajayi Happiness Okunọla gbe niluu Fayẹmi ti i ṣe Iṣan-Ekiti, o si ya ni lẹnu pe ẹni to ni oun gba iwe-ẹri ọmọwe ninu ẹkọ ogun jija ko le ṣe nnkan kan si i.

 

‘‘Eyi fi han pe ti ko ba jẹ pe Gomina Fayẹmi ko kunju oṣuwọn, o jẹ pe ko bikita ni, ọrọ ibo 2023 lo n ba kiri.’’

Adeyanju fi kun un pe asiko tawọn ajinigbe ji ọmọ ilẹ China kan lopin ọdun to kọja lo yẹ ki Fayẹmi ti gbe igbesẹ nitori Ado-Ekiti ni wọn ti gbe e.

O waa pe awọn eeyan Ekiti, o ni ki wọn bẹ gomina ko ṣiṣẹ ti wọn gba a fun, kawọn ajinigbe too maa wọle lọọ gbe awọn eeyan.

Leave a Reply