Nitori pe o sọrọ si gomina lori Fesibuuku, ijọba ni  ki olukọ kan lọọ rọọkun nile l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Olukọ kan to n ṣiṣẹ nileewe Maṣifa Community Grammar School, Maṣifa-Ile, nipinlẹ Ọṣun, Philip Akinyẹmi, ni wọn ti ni ko lọ rọọkun nile bayii lori ẹsun pe o n sọrọ buruku si Gomina Adegboyega Oyetọla lori ẹrọ ayelujara, to si mu ọrọ oṣelu lọkun-un-kundun ju iṣẹ olukọ to n ṣe lọ.

Ninu lẹta idaduro Philip ti Alaroye ri, ọfiisi eto ẹkọ to wa ni Iwọ-Oorun Ọṣun lo kọ lẹta naa si i logunjọ, oṣu kejila, ọdun 2021, pẹlu nọmba OSWEDO/AD/2021/5057005.

A gbọ pe awọn ti ọfiisi alakoso apapọ fun awọn olukọ l’Ọṣun, Tutor General, ti kọkọ kilọ fun Philip ko too di pe ọrọ rẹ pada yọri si irọọkun nile yii.

Ninu iwe ‘Wi tẹnu ẹ’ ti wọn fi ranṣẹ si olukọ naa ni wọn ti sọ pe, “Oniruuru ọrọ ti o n kọ sori Fesibuuku jẹ eyi to le da wahala silẹ, o si han gbangba pe o ti yẹsẹ kuro loju ọna iṣẹ tijọba gba ọ fun.

“Ọrọ oṣelu lo ku ti o gbaju mọ ju iṣẹ olukọ tijọba gba ọ fun lọ, o si ti n ṣe lodi si iwa to yẹ ki oṣiṣẹ ijọba ma a hu. Awọn nnkan ti o n gbe sori ayelujara jẹ awọn nnkan arifin sijọba ati gomina to n sanwo oṣu rẹ loorekoore.

“Iwadii fi han pe aimọye eeyan ni wọn ti ki ọ nilọ, to fi dori awọn ẹlẹgbẹ rẹ, ọga agba ileewe rẹ, ṣugbọn etiikun lo kọ si wọn.”

Lẹyin iwadii si ọrọ Philip ni ileeṣẹ eto-ẹkọ paṣẹ pe ko lọ rọọkun nile lori ẹsun hihuwa ikọlu si awọn alaṣẹ (Public Assault)

Lẹta naa sọ siwaju pe olukọ naa ko gbọdọ wa si sakaani ileewe ọhun lai ṣe pe ijọba ranṣẹ si i.

Leave a Reply