Nitori pe ọrẹbinrin mi n gbe ‘kinni’ rẹ sa fun mi lemi atawọn ọrẹ mi ṣe fipa ba a lo pọ-Ismaila

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ismaila Raheem, ẹni ọdun mejilelogun, ti sọ pe nitori ọrọ alufansa ti ọrẹbinrin oun maa n sọ si oun lo fa a ti oun fi pinnu lati fipa ba a lo pọ.

Lasiko ti Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, n ṣafihan Ismaila atawọn ọrẹ rẹ meji;  Ẹriayọ Fọlọrunṣọ, ẹni ọdun mọkanlelogun ati Akintọla Ṣangokunle toun naa jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun, ni Ismaila sọ pe oun ti huwa naa tan ki oju oun to walẹ.

Ṣaaju ni Ọlọkọde ti sọ pe adigunjale ati ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn afurasi mẹtẹẹta naa, ati pe ọjọ ti pẹ ti wọn ti n yọ awọn eeyan agbegbe Oke-Baalẹ, niluu Oṣogbo, lẹnu.

Kọmiṣanna fi kun ọrọ rẹ pe papanbari iwa awọn afurasi naa ni bi ọkan lara wọn, Ismaila, ṣe ko awọn ọrẹ rẹ mejeeji lọ si agbegbe Kajọla, niluu Oṣogbo, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ti wọn si lọọ fipa ba ọmọbinrin kan sun lẹyin ti wọn gba foonu ati owo lọwọ rẹ.

Ṣugbọn nigba to n sọ tẹnu rẹ, Ismaila, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Agogo, sọ pe ọrẹbinrin oun ni ọmọ naa, ati pe o ti to oṣu mẹfa ti awọn ti n ba aniyan ifẹ bọ, ti ko si faaye gba ki oun fi ọwọ kan an rara.

“Agunmu ni mo n ta niluu Oṣogbo, o si ti to oṣu mẹfa ti emi ati ọmọbinrin yẹn ti n fẹra wa. Mo maa n fun un lowo loorekoore, n ko si le sọ pato apapọ iye owo ti mo ti fun un.

‘‘Ṣugbọn pẹlu bi mo ṣe n fun un lowo to, ti mo ba ni ka jọ ṣere oge, o maa ni oun ko ṣe. ‘‘Nigba ti mo pe e titi lo sọ fun mi lọjọ kan pe mo kere si ẹni ti oun le fẹ. Eyi lo fa a ti emi ati ọrẹ mi fi wa a lọ. Emi ni mo lọ sile rẹ, mo ba ọmọkunrin kan nibẹ, mo si pe ọrẹbinrin mi yii jade, mo ni mo fẹẹ ri i. Bo ṣe jade si mi ni mo tan an lọ si kọrọ kan, mo si fipa ba a lo pọ. Lẹyin ti mo ṣetan lọrẹ mi naa tun ba a sun.

‘‘Nigba to ya, mo wa a lọ sile, mo si bẹ ẹ pe ko ma binu, pe nitori igbo ti mo ti mu ki n too wa sọdọ rẹ ni. Mo ni ko jọwọ dariji mi. Mo si sọ ibi ti mo wa to ba fẹẹ ri mi fun un.

‘‘Emi o mọ pe o ti lọọ fẹjọ mi sun lagọọ ọlọpaa, oun naa lo si mu awọn ọlọpaa wa si ibi ti mo wa ti wọn fi mu mi.’’

Leave a Reply