Nitori pe wọn ko kunju osunwọn, ijọba wo awọn ile ounjẹ kan danu n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu ironu lawọn oludasilẹ ileeṣẹ burẹdi atawọn ileetaja ounjẹ igbalode kan wa bayii pẹlu bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe ti ileeṣẹ burẹdi marun-un ati ile ounjẹ igbalode meji kan pa nI’badan.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nileeṣẹ to n mojuto eto ilera ati imọtoto ayika ninu ijọba ipinle Ọyọ gbé igbesẹ naa ninu abẹwo to ṣe kaakiri awọn ile ounjẹ nigboro Ibadan.

Ọga agba to n ri si ayẹwo ounjẹ, omi atawọn nnkan to rọ mọ ọn, Abilekọ Afusat Akande, ẹni to ko awọn ikọ olubewo naa sodi, fidi ẹ mulẹ pe nitori pe awọn ileeṣẹ naa ko kunju oṣuwọn lati se ounjẹ fawọn araalu jẹ nijọba ṣe fiya naa jẹ wọn.

Bakan naa lo ni awọn to lawọn ileeṣẹ ọhun kọ lati forukọ ayika ti wọn ti n pese awọn ohun jijẹ wọnyi silẹ lọdọ ijọba.

“Nise lawọn to n ra ounjẹ aladun jẹ nita n fojoojumọ pọ si i. Idi niyi ta a fi ni lati mojuto awọn ohun jijẹ yii daadaa”, bẹẹ l’Abilekọ Akande sọ.

O fi kun un pe ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ọyọ ni lati fẹsẹ ofin ọdun 2012, eyi to n ri si imọtoto ounjẹ, omi atawọn nnkan to rọ mọ ọn mulẹ, paapaa pẹlu bi orileede yii ṣe n koju àìsàn onigba-meji ati aisan iba lasa lọwọ.

Bakan naa lo fi dandan le e fawọn ile ounjẹ gbogbo nipinlẹ Ọyọ lati maa ṣayẹwo imọtoto ileeṣẹ wọn lọdọ ijọba laarin oṣu mẹfa mẹfa, ki wọn ma baa fi aiṣedeede tiwọn kọ àìsàn ba araalu.

Leave a Reply