Nitori rogbodiyan Jos, ijọba ko awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ ipinlẹ Kwara pada sile 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Yoruba ni koju ma ribi, gbogbo ara loogun ẹ, nitori rogbodiyan to n lọ lọwọ nipinlẹ Plateau, ijọba ipinlẹ Kwara ti lọọ ko awọn ọmọ bibi ipinlẹ Kwara, to n kẹkọ niluu naa pada sile, fun aabo ẹmi ati dukia wọn.

Iroyin to tẹ ALAROYE, lọwọ ni pe ko din ni akẹkọọ mejidinlọgọta tijọba ti ko pada wale bayii pẹlu ọkọ bọọsi akero mẹrin ọtọọtọ, ti awọn ẹsọ alaabo si wa pẹlu wọn ninu irin-ajo naa.

Tẹ o ba gbagbe, ipinlẹ Plateau ti wa ninu ipayinkeke lati ọjọ ti awọn agbebọn ti da ẹmi awọn arinrin-ajo to n lọ bii mejilelogun legbodo nipinlẹ naa, ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga Fasiti ilu Jos, si ti mu idaduro ba idanwo ileewe ọhun to n lọ lọwọ, ti gbogbo awọn ipinlẹ jake-jado Naijiria si n lọọ ko awọn eeyan wọn kuro nipinlẹ naa.

Aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ ipinlẹ Kwara (NAKSS), Muftau Mubarak Shittu, ti waa gboriyin fun ijọba nitori igbese ọhun.

Leave a Reply