Nitori rogbodiyan SARS: TINUBU KO SI WAHALA TUNTUN!

Awọn ọlọpaa SARS ni wọn kọkọ sọ pe awọn ko fẹ, nigba tijọba si ri i pe ọrọ naa fẹẹ le ju bẹẹ lọ, wọn sare kede pe awọn ko le pa ọlọpaa SARS rẹ, nitori iṣẹ ti wọn n ṣe fawọn pọ. Eyi tubọ mu ki ori awọn ọmọ yii kanrin, wọn si ni ko buru o, a jẹ pe awọn ko kuku ni i kuro nibi ti awọn wa, ki ijọba fọwọ mu SARS tirẹ, ki awọn naa si maa ṣe tawọn lọ. Nigba ti awọn ọmọ naa ko si lọ loootọ, ijọba tun sare kede pe o daa, awọn ti pa ọlọpaa SARS run, awọn ko ni i ko wọn jade mọ, ki awọn ọdọ naa maa pada sile wọn. Ṣugbọn awọn ọdọ yii fura pe ijọba le maa tan awọn, wọn si tun tẹsẹ duro diẹ. Ọrọ ti wọn si wi ṣẹ o, nitori lojiji ni ijọba tun kede pe awọn ti da SWAT silẹ, iyẹn ni awọn yoo maa lo bayii. Ọrọ naa dun awọn ọmọ yii, nitori wọn mọ pe ijọba yoo kan tun ko awọn ọlọpaa SARS sinu SWAT ni, iyẹn ni pe wọn kan n ta awọn ni.

Ẹtan yii lo jọ pe o bi awọn ọmọ yii ninu, ni wọn ba kuku ni ki i ṣe ọrọ ọlọpaa SARS nikan lawọn n beere fun mọ, tabi ti awọn n tori ẹ ṣe iwọde, awọn n fẹ ijọba to dara, ki awọn ti wọn n ṣejọba Naijiria ṣalaye fawọn ati gbogbo aye, eto ti wọn ni fun ijọba rere ni Naijiria, nigba naa lawọn yoo too fi oju popo silẹ. Eleyii ba awọn ti wọn n ṣejọba lẹru gan-an, nitori wọn mọ pe iru awọn nnkan bayii a maa da wahala silẹ lagbaaye, a si maa ko ba ijọba orilẹ-ede ti wọn ba ti ṣe bẹẹ. Nitori idi eyi, wọn bẹrẹ si i wa gbogbo ọna lati pana ọrọ yii, wọn ni kawọn ọmọ yii kuro ni titi, wọn ko si tete mọ bi wọn yoo ti ṣe e. Ọlọpaa ko ṣe e lo, nitori awọn ọmọ naa pọ ju awọn ọlọpaa lọ, bi ija ba si de, bo tilẹ jẹ wọn ko mura ija, yoo ṣoro ki apa ọlọpaa too ka wọn. Gbogbo awọn eto mi-in ti wọn mọ ni wọn sare ṣe, ṣugbọn ko bọ si i.

Nigba naa ni wọn ronu awọn ṣọja, ti ileeṣẹ ologun kede pe awọn ti bẹrẹ eto kan ti wọn n pe ni Ẹrin Ahanrinhan, (Operation Crocodile Smile) nibi tawọn yoo ti ko awọn ṣọja kaakiri origun Naijiria, nitori eto igbaradi ti awọn maa n ṣe lọdọọdun ni. Bo tilẹ jẹ pe ọga ṣọja pata, Tukur Burutai, kede pe ki i ṣe nitori awọn ọmọ ti wọn n ṣewọde lawọn ṣe n ko awọn ṣọja naa bọ, ko sẹni to gba wọn gbọ, wọn ni o ṣe jẹ asiko yii, ati ninu ọsẹ ti awọn ọmọ yii n ṣewọde wọn, ni awọn ṣọja Naijiria fẹẹ bẹrẹ igbaradi lagbegbe ti wọn ti n ṣewọde yii, bawo ni awọn ọdọ yii ati awọn ṣọja naa ko ṣe ni i kọ lu ara wọn. Nigba ti wọn si ti kede iṣẹ igbaradi tuntun fun awọn ṣọja yii ni gbogbo aye ti bẹrẹ si i reti ohun ti yoo ṣẹlẹ, ti awọn ọlọmọ si n kilọ fun ọmọ, nigba tijọba ipinlẹ Eko si kede ofin konilegbele tuntun, ohun meji lo sare ṣẹlẹ laarin wakati diẹ lọjọ naa.

Ọpọ awọn ti wọn jẹ gbajumọ oṣere, boya onitiata tabi olorin ti wọn n ṣe atilẹyin fun awọn to n ṣewọde naa, ti n ba ara wọn sọrọ pe ko ni i daa lati tẹ ofin ijọba loju, ki awọn kuku maa lọ, ṣugbọn bi isede naa ba ti n pari bayii, ki awọn tun maa pada bọ ni. Ọkan pataki ninu awọn ti wọn ṣe ikede yii ni ọmọ agbalagba lọọya nni, Fẹmi Falana, ti wọn n pe ni FALZ, ti oun jẹ akọrin. Bi oun ti wi, bẹẹ ni Ṣeun Kuti, Mista Makaroni, ati awọn mi-in ninu wọn sọ si ori ẹrọ ayelujara wọn. Awọn yii si kuro ni titi, wọn pada si ile wọn. Ṣugbọn nidakeji, awọn ọdọ kan ta ku sibẹ, wọn ni awọn ko ni i lọ, kaka ki awọn maa rin kiri, awọn yoo kuku sọ ibi iwọde naa, ni Too-geeti Lẹkki di ile awọn, awọn yoo si maa ṣe konilegbele tawọn nibẹ, lai ni i si wahala kankan.

Bẹẹ lawọn wa nibẹ, ti wọn si ta asia orilẹ-ede Naijiria siwaju, ti wọn jokoo jẹẹ lai ba ẹnikẹni ja, to jẹ orin orilẹ-ede Naijiria nikan ni wọn n kọ. Kinni naa ti n lọ wẹrẹwẹrẹ bẹẹ, bi wọn si ti wa ti ilẹ fi ṣu pata niyi. Bi ilẹ ti ṣu pata ti ẹni kan ko ri ẹni kan mọ ni girigiri naa ṣẹlẹ, ko si si ẹni to le ṣalaye ọrọ naa gan-an bo ti ri ati bo ti jẹ. Ohun ti tọkunrin-tobinrin ti wọn n ṣewọde naa yoo maa ro lọkan ara wọn, ti ọpọ awọn araalu naa yoo si maa ro pẹlu ni pe awọn mọto ṣọja yoo tẹle ara wọn lati waa tu wọn ka ni, bi wọn ba si n bọ bẹẹ, wọn yoo ko ibọn dani, ati mọto akọtami, ti wọn yoo si to lọwọọwọ bii ẹni to n lọ soju ogun. Wọn ti ro pe ọga to ba ṣaaju awọn ṣọja naa yoo bọ silẹ lati kilọ fun awọn pe kawọn tuka, bi awọn ko ba si gbọ, ohun to ba ṣẹlẹ, awọn naa yoo foju ri i. Ṣugbọn eleyii ko ri bẹẹ rara.

Lojiji ni kinni naa ṣẹlẹ. Awọn eeyan naa kan ya bo wọn ni, afi gbau gbau, iro ibọn. Awọn kan ni ọkada ni wọn gbe wa, awọn kan ni mọto ni, awọn kan ni wọn ti sa pamọ si adugbo naa tẹlẹ ni. Ko si ẹni to mọ bi awọn ṣọja naa ṣe de si aarin awọn ti wọn n ṣewọde, iro ibọn, ati girigiri to tẹle ẹ lo jẹ ki awọn eeyan mọ pe wọn ti de. Wọn ni aṣọ ologun ni wọn wọ, aṣọ kan naa ni gbogbo wọn si wọ, gẹgẹ bi fidio ti ṣe afihan rẹ. Ariwo ibọn, ariwo awọn ọdọ, igbe oro lẹnu awọn eeyan. Akọlukọgba to waye naa buru to fi di ohun ti gbogbo aye n pariwo rẹ, nitori ẹni to ba wo fidio naa yoo gbọ igbe oro ti awọn eeyan n ke, yoo si ri bi awọn eeyan ti n sare fun ẹmi wọn. Bi wọn ti n sare lawọn ṣọja yii n pa wọn ti wọn ko si tori ẹ dawọ ibọn wọn duro.

Awọn eeyan ti ro pe wọn yoo ri aworan ohun to ṣẹlẹ lọjọ keji, nitori kamẹra to n ya fọto awọn eeyan wa ni Too-geeti Lẹkki yii, ko si si ohun ti yoo ṣẹlẹ nibẹ ti kamẹra yii ko ni i gbe e. Afi bi wọn ṣe gbọ pawọn eeyan kan ti waa yọ kamẹra yii danu lọwọ ọsan tẹlẹ, ati pe awọn eeyan yii kan naa lo ṣeto bi wọn ti ṣe lu ina gbogbo to wa ni Too-geeti yii pa lasiko tawọn ṣọja yii de, to fi jẹ inu ookun ni gbogbo ibẹ wa, ti ko si ẹni kan to ri ẹni kan, ti titi awọn eeyan naa fi ṣe aburu ti wọn waa ṣe. Dajudaju, oku sun rẹpẹtẹ loootọ, ṣugbọn wahala to kọkọ ṣẹlẹ ni pe ko si oku eeyan ti wọn ri nilẹ, awọn ti wọn mọ nipa iṣẹ ologun si sọ pe awọn ṣọja naa ti ṣeto lati gbe oku awọn eeyan naa lọ. Gbogbo ohun to ṣẹlẹ ni awọn ọdọ yii ti ro pe awọn yoo ri nijọ keji, nigba ti wọn ko si tun ri i lọjọ keji, iyẹn lẹyin ti awọn ṣọja yii ti lọ, ibinu awọn ọmọ naa ru soke.

 

Lẹsẹkẹṣe ni wọn kọ lu Too-geeti yii, ti wọn si dana sun un, nitori ariwo ti wọn n pa ni pe ileeṣẹ Tinubu ni. Wọn kuro nibẹ, wọn si bẹrẹ si i wa ileeṣẹ Tinubu mi-in kaakiri, ti wọn si n sọ ina si wọn, tabi ba ibẹ jẹ. Ohunkohun ti wọn ba ti darukọ Tinubu mọ, awọn oluwọde naa yoo rọ lọ sibẹ, wọn yoo si ba a jẹ. Nibi yii ni ọrọ ti daru mọ ijọba lọwọ, nitori ijọba ko le ko awọn ṣọja tabi agbofinro mi-in jade, nigba to jẹ eyi to ṣẹlẹ yii, gbogbo aye lo n pariwo pe ko si ijọba agbaye kan to n ṣe bẹẹ, wọn ko letọọ lati yinbọn pa awọn ti wọn n ṣewọde, awọn ijọba ilẹ-okeere si n da si i. Ọrọ naa ko wahala mi-in ba awọn to n ṣejọba tori wọn mọ pe ti wọn ba fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe awọn lawọn ṣe e, koda ki awọn ti fi ijọba silẹ, wọn le mu awọn, ti wọn yoo si ba awọn ṣe ẹjọ apaayan ni kootu agbaye, bi wọn ko ba si ṣọra, ẹwọn ni wọn yoo ku si.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ko tilẹ ran ijọba apapọ funra ẹ lọwọ, nitori niṣe lo jade pe oun ko mọ kinni kan nipa awọn ṣọja ti wọn lọọ kọ lu awọn ọmọ naa, o ni awọn ti wọn lagbara ju oun lọ lo wa nidii ọrọ yii o. Lati le sọ pe awọn ti wọn lagbara ju oun lọ lo wa nidii ọrọ naa, awọn eeyan bẹrẹ si i fi eeji kun ẹẹta, wọn ni iṣẹlẹ naa ko le se lẹyin ijọba Buhari, pe ko ṣaa ti i pẹ nigba ti Lai Muhammed ti i ṣe minisita fun eto ikede sọ pe awọn ko ni i gba ki ẹnikẹni fi ọwọ pa ida ijọba awọn loju, ẹni ba ṣe bẹẹ, yoo jẹ iyan rẹ niṣu. Wọn ni pẹlu iru ikede ti Alaaji Muhammed ṣe yii, ko si ariyanjiyan pe ijọba Buhari lo da awọn tọọgi naa sita. Eleyii ko fi ọkan awọn ti wọn n ba Buhari ṣiṣẹ balẹ, awọn naa si jade pe ijọba apapọ ko mọ kinni kan nipa ọrọ naa, awọn ko ran ṣọja kankan niṣẹ o.

Bi awọn ti sọ bẹẹ ni ọga awọn ṣọja pata jade, oun naa ni oun ko mọ kinni kan ninu ọrọ yii, ko si si ileeṣẹ ologun kan to paṣẹ fun awọn ṣọja lati jade, tabi lati ko ibọn lọ si Lẹkki, o ni ṣaka ni ara awọn mọ ni tawọn. Ọga awọn ọlọpaa pata naa jade, o ni ko si ẹni to jade ninu awọn ọmọ toun to lọ si ọna Lẹkki, ko si sọlọpaa kan to ni ibọn ti yoo yin danu bẹẹ yẹn, nitori bẹẹ ki ẹnikẹni maa gbe iru ọrọ bẹẹ de ọdọ oun. Ni gbogbo asiko yii, awọn oluwọde ko duro mọ, wọn ti gbinaya, wọn ti ba ileeṣẹ tẹlifiṣan TVC jẹ, wọn ti lọ si ileeṣẹ iwe iroyin The Nation, bẹẹ ni wọn n wa awọn ileeṣẹ Tinubu mi-in kaakiri. Idi eyi ni pe nigba ti ijọba ti ni awọn kọ lawọn ran awọn eeyan yii, to si jẹ ileeṣẹ ọmọ Tinubu, Too-geeti ni wahala yii ti bẹrẹ, awọn mi-in ni o ṣee ṣe ko jẹ Tinubu gan-an lo wa nidii ẹ, Tinubu lo ran awọn ṣọja, bo si jẹ janduku to wọ aṣọ ologun ni wọn, pe ki wọn lọọ pa awọn ọmọọlọmọ.

Ko sẹni to waa mọ ibi ti awọn ọmọ to n ṣe iwọde naa ti ri nọmba Tinubu, ni wọn ba pe e lori foonu, ni wọn ba bẹrẹ si i bi i leere pe ki lo de to ni ki wọn pa awọn eeyan, ki lo de to ni ki wọn pa awọn ọmọ ọlọmọ, nigba ti oun naa bimọ. Akọkọ, Tinubu ni oun ko si nile o, pe irin-ajo, ni orilẹ-ede Faranse, loun wa, ati aṣaaju ilu loun, oun ko jẹ si nidii iru iwa yii, oun ko si duro sibi kan pe ki wọn pa awọn ọmọọlọmọ. O ni eleyii ko daa, bẹẹ lo si fi ẹnu kan bu ijọba Buhari pe awọn ni wọn ko tete mojuto ọrọ naa ko too di ohun to da yii. Ko sẹni to waa mọ ohun to ṣẹlẹ lẹyin naa nitori ọrọ ti Tinubu sọ lori foonu ati ohùn to fi sọrọ yii yatọ pata si ọrọ to sọ ati ohùn to fi sọ ọ nigba to jade lọjọ Satide ijẹrin. Ohun ti awọn eeyan fura si ṣaa ni pe o ṣee ṣe ko jẹ ọrọ to kọkọ sọ bi awọn ọrẹ rẹ ti wọn n ṣejọba ninu.

Ṣe ni gbogbo igba naa, awọn eeyan ti bẹrẹ si i sọ oko ọrọ buruku ranṣẹ si Buhari pe ki lo de ti ko ba gbogbo ilu sọrọ, ki lo de ti ko wi kinni kan nipa ohun to n lọ. Buhari ko dahun sibẹ, afi nigba ti akọwe ijọba Amẹrika ni ohun to ṣẹlẹ ni Naijiria naa ko dara. Ni Buhari ba jade sọrọ, ṣugbọn ọrọ to sọ naa, tijatija ni, eebu ati ihalẹ lo pọ ninu ohun to sọ, koda, ko mẹnu ba ohun to ṣẹlẹ ni Lẹkki yii rara. Ohùn ti Buhari fi waa sọrọ yii naa ni Tinubu fi sọrọ nigba to jade, to lọọ ṣe abẹwo si Gomina Sanwo-Olu. Akọkọ, oun to ti ni oun ko si nile tẹlẹ tun sọ ọ loju aye pe wọn n parọ mọ oun ni, oun ko rebi kan, nitori Aṣiwaju Eko loun, oun si ni Jagaban. Ohun ti eyi ni i ṣe pẹlu gbogbo ohun to  wa nilẹ yii ko ye ẹni kan. Lẹyin eyi ṣaa, Tinubu sọ ọrọ to ka awọn eeyan lara gan-an.

O ni wọn gbọdọ wadii awọn ọdọ ti wọn lọọ ṣe iwọde ni Lẹkki yii. Ta lo ran wọn, kin ni wọn n wa, awọn wo lo n fun wọn lounjẹ, iru eeyan wo ni wọn, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eyi tumọ si pe Tinubu ko binu sawọn to paayan, ko si ba awọn ti wọn pa ọmọ wọn kẹdun, ohun to kan an ni lati mọ awọn ti wọn ṣewọde, ati bi wọn ṣe debẹ. Ọrọ naa ti di wahala gidi si ọrun Aṣiwaju, nitori bi araale ti n bu u, bẹẹ lawọn ero ọna n bu u, wọn ni ko laaanu, ika ati ọdaju gbaa ni. Awọn ti wọn mọ nipa oṣelu tilẹ ni bo ba jẹ nitori pe o n mura lati du ipo aarẹ lo ṣe n ṣe gbogbo eleyii, o ti fi ọrọ ẹnu ati iṣe rẹ ko ba ara rẹ, nitori iṣoro yoo wa fun un gidigidi lati de ipo to n wa yii gan-an, nigba to jẹ lojoojumọ lo n sọ ara rẹ di ọta awọn eeyan si i. Ṣugbọn awọn ọmọ Aṣiwaju ti ni awọn ọta ọga awọn lo wa nidii ọrọ yii o, Jagaban yoo si bori gbogbo wọn.

Leave a Reply