Nitori rogbodiyan to ṣẹlẹ laarin Hausa ati Yoruba n’Ibadan, Makinde ti ọja Ṣáṣá pa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori laasigbo to waye ni Ṣáṣá, n’Ibadan, lọjọ Ẹtì, Furaidee, ninu eyi ti ọpọ ẹmi eeyan ati dukia ti ṣegbe, ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Gomina Ṣeyi Makinde, ti ti ọja nla to wa lagbegbe naa pa.

Gẹgẹ bí Ọgbẹni Taiwo Adisa ti í ṣe Akọwe iroyin Gomina Makinde ṣe fìdí ẹ mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ́ sawọn oniroyin n’Ibadan laarọ ọọ Abamẹta, Satide, tọsan-toru nijọba fi ṣe e leewọ fún ẹnikẹni lati ṣe kárà-kátà ninu ọja naa bayii.

Ijọba ko fi gbèdéke kankan sí igbesẹ naa, wọn ni ko ṣaa gbọdọ ṣi kárà-kátà kankan nibẹ mọ titi dìgbà tí ìjọba yóò ṣi ọja naa pada lọjọ iwaju ti ẹnikẹni kò ti i le sọ.

Ninu rogbodiyan tó ṣẹlẹ laarin awọn Hausa ati Yoruba ní Ṣáṣá yii leeyan mẹrin ti ku, ti wọn sì dana sun ọkẹ àìmọye ile ati mọto pẹlu ọkada rẹpẹtẹ.

Oku eeyan meji ti wọn dana sun si ẹgbẹ títì ọna Ọ̀jọ́ọ̀ sí Mọ́níyà, ni Ṣáṣá, n’Ibadan, pẹlu ọkada meji, ṣi n jona lọwọ nigba ti akọroyin wa lọ síbẹ ni nnkan bíi aago mẹfa irọlẹ ọjọ Ẹti.

Leave a Reply