Nitori rogbodiyan to waye lawọn ibi kan l’Ondo, afurasi bii ogun ti wa lahaamọ ọlọpaa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn afurasi janduku bii ogun lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ latari ipa ti wọn ko ninu rogbodiyan to bẹ silẹ lori ọrọ ija oye to waye niluu Ikarẹ Akoko ati wahala to su yọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati OPC, ẹka tilu Ọwọ.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Bọlaji Salami, lo sọrọ yii lasiko to n fawọn oniroyin labọ abẹwo to ṣe si awọn agbegbe ti wahala ti waye niluu Ikarẹ Akoko ati Ọwọ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

O ni gbogbo awọn tọwọ tẹ ọhun lo ṣi wa lọdọ awọn, ti awọn si n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọ. O ni awọn ti pinnu ati ko awọn afurasi naa lọ sile-ẹjọ ni kete ti iyansẹlodi awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eto idajọ ba ti pari.

Kọmisanna ọhun ni ẹnikẹni ti iwadii awọn ba ti fidi rẹ mulẹ pe o lọwọ ninu rogbodiyan to waye lawọn ilu mejeeji ko ni i lọ lai jiya.

 

 

 

Leave a Reply