Nitori SARS, wọn wọ Fẹmi Falana lọ sile-ẹjọ agbaye

Aderounmu Kazeem

Ẹgbẹ kan ti wọn lawọn n fẹ daadaa fun Naijiria ti wọ Amofin agba nni, Fẹmi Falana, lọ sile-ẹjọ to n gbẹjọ iwa ọdaran lagbaye (ICC) lori ẹsun wi pe o n ṣatilẹyin fawọn ọdọ to ṣewọde tako SARS.

Orukọ ẹgbẹ to kọwe afisun nipa Falana, sile ẹjọ agbaye ọhun ni Make Nigeria Better Initiative (MNBI), ohun ti wọn lawọn duro fun gẹgẹ bi oruko wọn ni bi Naijiria yoo ṣe dara.

Ninu iwe ifisun ti agbẹjọro ẹgbẹ naa, Joseph Nwaegbu, kọ lorukọ ẹgbẹ ọhun si ile-ẹjọ giga agbaye lọjọ kẹrin, oṣu kọkanla, ọdun yii ni wọn ti ṣapejuwe ipa ti Falana ko ṣaaju iwọde ọhun, wọn ni o yẹ ki aye ri i gẹgẹ bi iwa ọdaran, to si yẹ ko jiya ẹ labẹ ofin.

Wọn ni niṣe ni Falana n pin awọn iroyin irọ kiri nipa ijọba, eyi to tubọ mu wahala ọhun fẹju gan-an.

Ọgbẹni Mark Dillion, olori awọn to wa lẹka iroyin kọọtu agbaye ọhun, sọ pe loootọ ni iwe ifisun ọhun ti tẹ awọn lọwọ, bẹẹ lo ti wa ninu akọsilẹ, ti igbesẹ to yẹ yoo si waye lori ifisun wọn.

 

One thought on “Nitori SARS, wọn wọ Fẹmi Falana lọ sile-ẹjọ agbaye

Leave a Reply