Ọlawale Ajao, Ibadan
Ko ni i pẹ, bẹẹ ni ko ni i jinna mọ bayii, ti awọn akọni ọmọ Yoruba meji nni, Aarẹ Ọna-Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ati ajijagbara fún iran Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo aye mọ si Sunday Igboho, yoo koju ara wọn ni kootu pẹlu bi ile-ẹjọ ṣe paṣẹ pe ki wọn fi iwe ipẹjọ pe Gani Adams wa si kootu.
Sunday Igboho lo pe Gani Adams lẹjọ, o lọkunrin naa ba oun lorukọ jẹ, bi ibanikorukọjẹ ọhun si ṣe ba oun lọkan jẹ to loun ṣe fẹ ki wọn fiya jẹ oun naa to, nitori naa, ki ile-ẹjọ paṣẹ fun olujẹjọ naa, to tun jẹ ọga awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, lati sanwo nla, miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (₦500 m).
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ohun ti olupẹjọ tori ẹ pẹjọ ko ṣẹyin akasilẹ ohun kan to jẹ itakurọsọ to waye laarin Gani Adams ati ọkunrin kan ti wọn pe ni Nuru Banjọ, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021, eyi ti awọn oniroyin kan gbe sori ẹrọ ayelujara laipẹ yii.
Ninu akasilẹ ohun naa la gbọ pe olujẹjọ ti ṣapejuwe olupẹjọ gẹgẹ bii apaayan to ṣokunfa iku gbajumọ oloṣelu kan lorileede yii, Oloye Bọla Ige.
Ṣugbọn Igboho sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iku ọkunrin naa, n lo ba gba kootu lọ, o ni kile-ẹjọ fiya nla jẹ ọga awọn OPC naa fun ẹsun ibanilorukọjẹ.
Lati oṣu to kọja lolupẹjọ ti pẹjọ naa, o si yẹ ki igbẹjọ ti bẹrẹ lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ṣugbọn eyi ko ṣee ṣe nitori olujẹjọ ko fara han ni kootu, bẹẹ ni ko si agbẹjọro tabi ẹnikẹni to ṣoju ẹ nile-ẹjọ.
Nigba ti igbẹjọ ọhun tun waye nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ti akọda kootu ṣalaye pe oun ko lanfaani lati fun olujẹjọ niwee ipẹjọ, nitori naa, ko jọ pe ọkunrin naa mọ pe ẹnikẹni pe oun lẹjọ si kootu yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti mo dele olujẹjọ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja, l’Ekoo, aṣọna rẹ to yọju si mi lati inu ile sọ pe ọga oun (Gani Adams) ko si nile”.
Lẹyin naa ladajọ kootu ọhun, Onidaajọ M.I. Sule, fun akọda ile-ẹjọ naa lanfaani lati lo ọnakọna mi-in to ba gba lati ri i pe iwe ipẹjọ ọhun tẹ ọga awọn OPC naa lọwọ.
Adajọ ni “Mo ti wo akọsilẹ gbogbo akitiyan akọda lati fun olujẹjọ funra rẹ niwee ipẹjọ, mo si ri i pe iwe ọhun ko ti i tẹ ẹ lọwọ nitori akọda ko ba a nile ẹ to wa l’Ojule kẹrinla, Opopona Ezekiel, loju ọna Toyin, n’Ikẹja. Nitori naa, mo pa a laṣẹ pe ki wọn lo gbogbo ọna yoowu ti olujẹjọ yoo fi mọ pe oun lẹjọ i jẹ ni kootu yii, koda, bo gba ki wọn lẹ iwe ipẹjọ naa mọ geeti ile tabi ara ogiri ile ẹ”.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Kẹfa, ọdun yii.