Nitori Sunday Igboho, awọn ọmọ Yoruba yoo ṣe iwọde ni London

Olufẹmi Iyanda, London

Aago mẹwaa owurọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni awọn ọmọ Yoruba kaakiri ilẹ Gẹẹsi fi iwọde lati ṣatilẹyin fun ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho si. Niwaju ile ijọba orileede naa to wa ni N0 10, Dowing Street, niwọde ọhun yoo ti waye.

Ninu atẹjade tawọn ọmọ Yoruba loke okun, paapaa awọn ti wọn n gbe ni ilẹ Gẹẹsi fi sita ni wọn ti kilọ pe nnkan kan ko gbọdọ ṣe Sunday Igboho, bẹẹ ni wọn rọ orileede Benin pe ki wọn ma ṣe fa Sunday le ijọba Naijiria lọwọ nitori wọn le pa a.

Tẹ o ba gbagbe, oru ọjọ Aje, Mọnde, mọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ mu Oloye Sunday Igboho ni papakọ ofurufu orileede Olominira Benin, nigba ti wọn lo fẹẹ sa lọ si oke-okun.

Ko too di asiko yii ni awọn DSS ti ṣakọlu silẹ ọkunrin naa to wa laduugbo Soka, niluu Ibadan, ti wọn si pa eeyan meji nibẹ lẹyin ti wọn ba gbogbo dukia rẹ jẹ, ti wọn si tun ko awọn ọmọ ẹyin rẹ mẹtala lọ.

Leave a Reply