Nitori Sunday Igboho, ẹgbẹ Agbẹkọya fẹhonu han n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹgbẹ Agbẹkọya kaakiri ilẹ Yoruba ti rọ awọn ọba alade gbogbo ilẹ naa lati ba Aarẹ orileede yii, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, sọrọ, ko le fi ajafẹtọọ ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, silẹ ninu ahamọ to wa lorileede Benin.

Ninu iwọde ti wọn ṣe lọ si Aafin Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanni Adetunji,  lati ri i daju pe ijọba apapọ ilẹ yii ati ti Benin yọ Sunday Igboho kuro ninu atimọle ni wọn ti sọrọ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun 2021 yii, lawọn agbofinro orileede Benin mu Oloye Adeyẹmọ ni papakọ ofurufu wọn nibẹ. Latigba naa lo si ti wa  lahaamọ wọn lorileede naa titi di ba a ṣe n wi yii.

Ṣaaju nijọba orileede Naijiria nibi ti ran awọn agbofinro lọọ ko ogun ja ajijagbara ilẹ Yoruba yii mọle, to jẹ pe Ọlọrun ni ko fi ẹmi ẹ le wọn lọwọ pẹlu bi wọn ṣi yinbọn pa meji ninu awọn alatilẹyin rẹ ti wọn wa ninu ile pẹlu ẹ lọjọ naa.

Lẹsẹkẹsẹ ti okiki ìròyìn ọhun kan pe wọn mu un lorileede Benin nijọba Naijiria ti sare ranṣẹ si ijọba orilede naa pe ki wọn yọnda ajijagbara ilẹ Yoruba naa fawọn nitori o pẹ ti awọn ti n wa a lati mu un fun iya jẹ.

Ṣugbọn bo tilẹ jẹ pe ijọba Benin ko fa a le ijọba apapọ ilẹ yii lọwọ, sibẹ, wọn ko ti i fi i silẹ ninu ahamọ wọn lọhun-un latigba naa. Eyi lo si n ta awọn Agbẹkọya lara pe wọn ti jẹ ki ọmọ iya awọn pẹ ju latimọle, afi ki wọn yaa fi i silẹ ni kikaia.

Lati gbọngan Mapo, n’Ibadan, ni wọn ti bẹrẹ iwọde ọhun, ti wọn si fẹsẹ rin wọọrọ lọ si aafin Ọba Adetunji laduugbo Popo Yemọja, nigboro Ibadan, kan naa.

Bo tilẹ jẹ pe Olubadan ko si lori itẹ lati gba wọn lalejo, Ayaba Adetunji tẹwọ gba lẹta ti wọn mu wa fun ọba naa.

Koko meje ni wọn kọ sinu lẹta ọhun. Ninu ẹ ni ibeere fun itusilẹ Sunday Igboho, atunṣe si iwe ofin orileede yii, ikilọ fun ijọba Buhari lati jawọ ninu ipinnu rẹ lati yọ owo iranwọ kuro lori epo rọbi ati bẹẹ bẹẹ lọ. 

Aarẹ Agbẹkọya, Oloye Kamorudeen Arẹmu Okikiọla, ẹni to fi lẹta ọhun le Ayaba Adetunji lọwọ, ṣalaye pe “awa Agbẹkọya ko bẹbẹ fun Oloye Sunday Adeyẹmọ nitori a mọ pe nitori ẹtọ Yoruba ti Sunday Igboho to n ja fun ni wọn ṣe ti i mọle, ko paayan, ko jiiyan gbe, bẹẹ ni ko huwa  kankan to lodi sofin. A wa lati sọ fun un pe a ko le fara mọ iya ti wọn fi n jẹ Sunday Igboho mọ ni.

“Igbagbọ wa ni pe awọn ọba yoo le ba Aarẹ Buhari sọrọ, yoo si le gbọ si wọn lenu. Idi ree ta a ṣe waa ran baba wa Olubadan si wọn. Ba a si ṣe wa sọdọ Olubadan yii naa la n lọ sọdọ awọn olórí ọba yooku nilẹ Yoruba bii Ọọni ti Ifẹ, Alaafin Ọyọ, Alake ti Ẹgba, Deji ti Akurẹ ati Ewi ti Ado-Ekiti. 

“Ta a ba waa ṣeyi, ti wọn tun kọ lati tu Sunday Igboho silẹ, nigba naa la maa jẹ ki ijọba Naijiria mọ iru ẹgbẹ ti wọn n pe ni Agbẹkọya.”

Nigba to n sọrọ lorukọ Ọba Adetunji, Akọweeroyin ori ade naa, Ọgbẹni Adeọla Ọlọkọ, ẹni to ṣapejuwe ẹgbẹ Agbẹkọya gẹgẹ bii akinkanju ọmọ Yoruba, fi wọn lọkan balẹ pe kiakia l’Olubadan yoo gbe igbesẹ lori lẹta naa lati jẹ ko tẹ Aarẹ Buhari lọwọ.

Bakan naa lo sọ pe Olubadan yoo ba awọn ọba yooku nilẹ Yoruba jiroro lori ọna ti wọn yoo gba yọ Sunday Igboho kuro ninu ahamọ.

O waa kan saara si wọn fun bo ṣe jẹ pe wọọrọ ni wọn ṣe iwọde naa lai huwa jagidijagan rara.

Diẹ ninu awọn eekan inu ẹgbẹ Agbẹkọya to kopa ninu iwọde ọhun ni Dokita Ọtunba Adegbenro Oguntọna, ti i ṣe akọwe apapọ ẹgbẹ naa, Iyalode Agbẹkọya atawọn alaga ẹgbẹ ọhun kaakiri awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba pẹlu gbajugbaja oṣere tiata nni, Adewale Abdul Razaq, ti gbogbo eeyan mọ si Sokoti Alagbẹdẹ Ọrun.

Leave a Reply