Nitori Sunday Igboho, ijọba fẹẹ fofin de ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, wọn fẹẹ kede ẹ bii ẹgbẹ afẹmiṣofo

Faith Adebọla

Pẹlu ibi ti ọrọ ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho de duro bayii, gbogbo ọna nijọba n ṣan lati gbegi dina erongba ati igbesẹ idasilẹ Orileede Oodua, iyẹn Yoruba Nation, tọkunrin naa n polongo rẹ, ki wọn si fi pampẹ ofin gbe e janto.

Igbesẹ mi-in ta a gbọ pe ijọba apapọ n gbero lati gbe bayii ni pe wọn fẹẹ kede ẹgbe Ilana Ọmọ Oodua bii ẹgbẹ afẹmiṣofo, ki wọn si fofin de ẹgbẹ naa, ati ki awọn ọlọpaa ati ọtẹlẹmuyẹ agbaye le ba wọn mu Sunday Igboho nibikibi to ba wa.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti Ọgbẹni Umar Gwandu, Oluranlọwọ pataki si Minisita feto idajọ nilẹ wa, Amofin agba Abubakar Malami, ṣe fun ileeṣẹ iweeroyin Punch lopin ọsẹ yii, ọkunrin naa ni gbogbo ohun to ba gba nijọba maa fun un lati bori awọn ti wọn n ja fun pinpin orilẹ-ede, tabi ti wọn lawọn fẹẹ ya lọ, o ni ijọba o ni i gba iru nnkan bẹẹ laaye.

“Ko sohun tijọba o le ṣe lati pa awọn to fẹẹ ya kuro yii lẹnu mọ, oriṣiiriṣii igbesẹ la si n gbero lati gbe, a o ni i ṣe ohun ti ko bofin mu, ṣugbọn gbogbo ohun to ba gba la maa fun un lati ri i pe ohunkohun tabi ẹnikẹni ko jin iṣọkan ati wiwa papọ orileede yii, lẹsẹ.”

Nigba ti wọn bi i lere boya ijọba ṣi wa lẹnu bi wọn ṣe fẹẹ gbe Sunday Igboho kuro ni orileede Bẹnẹ lati waa jẹjọ ni Naijiria, o ni oun o le sọrọ lori iyẹn, nnkan aṣiri ni, ki i ṣe gbogbo aṣọ ọrọ naa lawọn le sa loorun.

Amọ ṣa o, Olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe oun ko ro pejọba le gbe iru igbesẹ bẹẹ lati fofin de ẹgbẹ awọn, tabi ki wọn pe ẹgbẹ naa ni afẹmiṣofo, o ni bii igba tijọba ba fẹẹ fira wọn ṣẹlẹya ni, oun o si ro pe wọn le ṣe’ru nnkan bẹẹ.

Agbẹnuṣọ fun baba ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun naa, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ, sọ pe “tijọba ba fẹẹ ṣe’ru ẹ ni, ṣebi wọn mu awọn ọmọ ẹgbẹ wa ti wọn lọọ ṣewọde Yoruba Nation l’Ọjọta laipẹ yii, wọn si wọ wọn dele-ẹjọ, ṣugbọn wọn o fẹsun kan wọn pe ọmọ ẹgbẹ afẹmiṣofo ni wọn, tabi pe wọn fẹẹ doju ijọba de, wọn kan ni wọn n di alaafia ilu lọwọ ni, wọn si ti tu wọn silẹ lẹyin ọjọ diẹ.

Gbogbo igbesẹ ti ẹgbẹ wa n gbe la n fi han sojutaye, ko si ma-jẹ-a-gbọ tabi iditẹ nibi kan, wọọrọwọ la n ṣe awọn eto wa, gbogbo ilakaka wa ni pe ki ilẹ Yoruba di ibi tawọn ọmọ Yoruba yoo ti gbadun igbe aye rere ti awọn baba wọn ṣiṣẹ fun, ko si sẹnikẹni to le di wa lọwọ iyẹn, ko pọn dandan ka wa lara Naijiria ti ko rọgbọ yii,” bẹẹ lọkunrin naa sọ.

Bakan naa ni Alagba Ayọ Adebanjọ, Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, sọrọ lori ọrọ yii pe ijọba ko letọọ lati fofin de ẹgbẹ eyikeyii ti ko ba ti tẹ ofin loju tabi lọwọ ninu iwa ọdaran kankan. O ni ijọba onikumọ nikan lo le ṣe’ru nnkan bẹẹ.

“Ki lo de ti Alaṣẹ ilẹ Britain, Boris Johnson, ko fofin de ẹgbẹ Scottish Nationalist Party, latigba ti ẹgbẹ naa ti n polongo ominira fun awọn ọmọ ilẹ Scothland kuro lara United Kingdom? Ijọba le ma nifẹẹ si Sunday Igboho tabi Akintoye o, ṣugbọn wọn lẹtọọ lati wa, wọn lẹtọọ lati sọrọ, wọn si lẹtọọ lati sọ ohun to wu wọn lọkan. Ijọba ni o lẹtọọ lati fofin de wọn, iwa ta-ni-maa-mu-mi niru ẹ, ko ba eto ijọba awa-ara-wa mu rara.”

Leave a Reply