Nitori Sunday Igboho, wọn ṣewọde lọfiisi aṣoju orileede Bẹnẹ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Ọgọọrọ awọn alatilẹyin ti ya bo ọfiisi aṣoju orileede Olominira Benin, to wa lagbegbe Victoria Island, l’Erekuṣu Eko, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kejila yii. Wọn lọọ fẹhonu han ta ko bi ijọba orileede naa ṣe mu gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, sahaamọ, lorileede wọn.

Lajori ohun tawọn oluṣewọde naa n beere fun ni pe kijọba Benin da Sunday Igboho silẹ lahaamọ, ki wọn si fun un lominira pada.

Oriṣiiriṣii akọle ni wọn kọ sara aṣọ ti wọn wọ, pako ati iwe fẹrẹgẹdẹ ti wọn gbe dani ka pe: “Ki lẹ ti Sunday Igboho mọle fun, ẹ tu u silẹ,” “Ẹ da Sunday Igboho silẹ,” “Oloye Sunday Igboho ko gbọdọ ku sahaamọ yin o,” “Bẹẹ ṣe ti Sunday Igboho mọle, ẹtọ ọmọniyan lẹ n tẹ loju,” “Ẹ ma ki ọrọ oṣelu bọ ọrọ Sunday Igboho, ẹ tu u silẹ,” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ọfiisi aṣoju naa to jade lati ba awọn eeyan ọhun sọrọ sọ pe Aṣoju orileede Benin, Ọgbẹni Thomas Adjani Adegnandjou, ko si larọwọto lati ba wọn sọrọ, ṣugbọn awọn yoo jiṣẹ wọn fun un to ba de, lati fi ibeere wọn ṣọwọ sawọn alaṣẹ orileede Benin.

Tẹ o ba gbagbe, latinu oṣu keje, ọdun yii, lawọn agbofinro orileede Benin ti mu Oloye Sunday Adeyẹmọ ati iyawo rẹ, Rọpo, sahaamọ, ṣugbọn wọn fi iyawo naa silẹ lẹyin ọjọ mẹta, obinrin naa si ti pada siluu Germany, toun ati ọkọ rẹ fẹẹ wọ baaluu lọ kiṣẹlẹ naa too waye.

Latigba naa ni Sunday Igboho ti wa lahaamọ wọn, bo tilẹ jẹ pe a gbọ pe orileede Naijiria ti n gbe igbesẹ bi ijọba orileede Benin yoo ṣe yọnda rẹ fawọn, ki wọn le gbe e wa si Naijiria lati ba a ṣẹjọ, lori ẹsun idaluru ati hihuwa to le doju ijọba de.

Leave a Reply