Nitori Sunday lgboho, awọn Fulani sa lọ sodọ Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Nitori bi akinkanju ọmọ Yorùbá nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tí gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ṣe fun wọn ni gbèdéke ọjọ meje pere lati fi ipinlẹ Ọyọ silẹ, awọn Fulani ti rawọ ẹgbẹ si ijọba ipinlẹ Ọjọ lati gba awọn lọwọ Igboho.

Seriki Fulani, nipinlẹ Ọyọ, Saliu Abdul-Kadiri, lo rawọ ẹbẹ yii lorukọ awọn Fulani ẹgbẹ ẹ lasiko abẹwo ti aṣoju ijọba ipinlẹ naa ṣe si i niluu Igangan lati wo bi nnkan ṣe bajẹ si lasiko rogbodiyan kan to ṣẹlẹ ninu ilu naa lọjọ Ẹtì, Furaidee, to kọja.

CP Sunday Odukọya ti i ṣe oludamọran pataki fun Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ lori eto aabo lo ṣoju gomina ninu abẹwo ọhun lọsan-an ọjọ Ajé, Mọnde, ọsẹ yii.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Furaidee to kọja ni Sunday Igboho lọọ ba ọba awọn Fulani sọrọ lati kilọ fun awọn eeyan ẹ lati dẹkun pipa ati jiji awọn Yoruba gbe, to si fún wọn ní gbedeke ọjọ meje lati fi ipinlẹ Ọyọ silẹ bi ikillọ naa ko ba ba wọn lara mu.

Ohun ti ALAROYE kọ gbọ ni pe lẹyin ti Igboho lọ tan lawọn Fulani kan bẹrẹ si i fapa janu, ti wọn si ṣa awọn agbẹ meji kan ti wọn n dari bọ jẹẹjẹ lati inu oko wọn ladaa pa.

Ṣeun lorukọ ọkan ninu awọn agbẹ ti awọn Fulani ṣe bẹẹ ran lọ sọrun apandodo. Ọmọ agboole Alagbogbo, niluu Igangan, ni wọn pe e.

Ṣugbọn lasiko abẹwo awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ, ọba awọn Fulani sọ pe awọn to tẹle Igboho lẹyin ni wọn da wahala silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nirọlẹ ọjọ Furaidee ni mo ri i ti awọn ọkọ kan to tẹle ara wọn wọ Igangan ti wọn si bẹrẹ si i beere pe nibo nile Seriki Fulani? Ile Seriki Fulani da?

“Bi ọkan ninu wọn ṣe sọrọ niyẹn, o ni Sunday Igboho lo waa ba ẹ lalejo, mo si mọ pe wa a ti máa gburoo ẹ tẹlẹ bó ò ba tiẹ tí ì rí i ri.

“O ni awọn waa kilọ fun mi ni, pe ki awọn eeyan mi yee pa awọn Yoruba. Nibi ti mo ti ni ki n maa sọ fun un pe awa Fulani ki i ṣe oniwahala, ati pe laipẹ yii ni wọn mu awọn Yoruba kan naa fun ẹsun ijinigbe, afi lojiji ti mo gbọ pau! pau! ti awọn kan yinbọn.

“Lẹyin naa ni Igboho funra rẹ jade siwaju to sọ pe òun fún wa lọjọ meje pere lati fi ipinlẹ Ọyọ silẹ. O waa fi ibọn sẹnu, o fi Ogun bura pe ti a ba dagunla si gbedeke ọjọ meje ti oun fun wa yii, nnkan ti oun máa fi oju wa rí kọ ni i daa.

“Lẹyin ti wọn lọ tan la ri í pé wọn ti dana sun awọn ile awọn eeyan wa kan. Bẹẹ ni wọn ṣe awọn bíi mẹta kan leṣe.”

O waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati waa gba awọn silẹ lọwọ Sunday Igboho nitori lati ọjọ to ti fún awọn ní gbedeke ọjọ meje lọkàn awọn ko ti balẹ mọ, to jẹ pe pẹlu inú-fuu-àyà-fuu lawọn fi n gbe.

Aṣoju Gomina Makinde, CP Odukọya waa fi awọn Fulani lọkan balẹ lati maa gbé ìgbé ayé wọn lọ lalaafia nibikibi ti wọn ba wa ni ipinlẹ Ọyọ, niwọn igba ti wọn ko ba ti huwa ọdaran

O ni awọn to ba n huwa to lodi sofin nikan ni ko saaye fún ni ipinlẹ naa nitori ijọba ko ni i fi ojuure wo iru wọn.

 

Leave a Reply