Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Iṣoro nla lo jẹ fawọn arinrin-ajo ti wọn gba oju ọna marosẹ Ikarẹ si Akungba Akoko kọja lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu bawọn akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin ṣe di gbogbo ọna to wọ ilu Akungba pa patapata lasiko ti wọn n ṣe iwọde ta ko awọn alaṣẹ ileewe wọn.
Idanwo ipari saa kin-in-ni to yẹ kawọn akẹkọọ ọhun bẹrẹ lọjọ naa ko ṣee ṣe mọ. Koda, ọgọọrọ awọn ẹṣọ alaabo ti wọn duro wamuwamu ti awọn oluwọde ọhun lo dena rogbodiyan ti iba waye nibi ti wọn ti n fẹhonu han.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ofin tawọn alasẹ fasiti naa fi lelẹ pe akẹkọọ ti ko ba ti i sanwo ileewe rẹ fun saa 2020/2021 pe perepere ko ni i ba wọn kopa ninu idanwo ti wọn fẹẹ bẹrẹ ọhun lo bi wọn ninu ti wọn fi mura ija pẹlu awọn olori wọn.
Awọn ọmọ ileewe ọhun ni iwa ọdaju ati ika ni bawọn alaṣẹ ṣe kuna ati ro bi nnkan ṣe n le fawọn eeyan lọwọlọwọ lorilẹ-ede yii latari eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ.
Wọn ni diẹ ṣiun ni wọn ṣi ri ninu wahala ti awọn yoo ba wọn fa ti wọn ba fi kọ jalẹ lati yi ipinnu wọn pada.
Ṣugbọn ninu ọrọ ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ fasiti ọhun ba wa sọrọ laṣiiri, o ni ko yẹ kawọn ọmọ naa tun gbiyanju lati fẹhonu han mọ nitori pe awọn alaṣẹ Fasiti Akungba ti kọkọ gba si awọn aṣaaju ẹgbẹ akẹkọọ lẹnu lati yọnda awọn ti ko ba tí ì sanwo ki wọn ba wọn ṣe idanwo.
O fi kun un pe wọn ti gba awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ wọle si ipele kin-in-ni nimọran ki wọn lo nọmba Jambu wọn ti wọn ko ba ti i ni nọmba idanimọ ti ileewe.
Nigba ti ifẹhonu han ọhun fẹẹ ba ọna mi-in yọ lawọn alaṣẹ sare fi atẹjade kan sita pe ki olukuluku awọn akẹkọọ naa tete pada sile wọn, nitori awọn ti tilẹkun ileewe wọn pa titi dọjọ mi-in, ọjọọre.
Ko ti i ju bii ọsẹ meji sẹyin tawọn alaṣẹ Fasiti Imọ Iṣegun to wa niluu Ondo naa kede titi ileewe ọhun pa nigba ti wọn n gbọ finrinfinrin pe awọn akẹkọọ fẹẹ fẹhonu han lodi si owo gegere ti wọn fi kun owo ti wọn n san.