Nitori ọlọkada to paayan, awọn ọdọ dana sun ọkada bii ogun n’Isọlọ

Adewumi Adegoke
Niṣe ni ọrọ di bo o lọ o yago ni agbegbe Isheri Road, ni Jakande Estate, Isọlọ, niluu Eko, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti awọn araadugbo naa dana sun ọkada bii ogun, iyẹn lẹyin ti ọlọkada kan gba ẹni kan, ti iyẹn si ku.
Ibinu ọrọ yii ni awọn ọdọ agbegbe naa fi tu jade, ti wọn si dana sun ọkada naa. Lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ si i dana sun awọn ọkada ti wọn rin si asiko naa. Njgba ti oloju yoo si fi ṣẹ ẹ, ọkada bii ogun lawọn eeyan naa ti mu balẹ, ti wọn dana sun un ku eeru.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ẹni to koro oju si idajọ lọwọ ara ẹni ti awọn ọdọ naa ṣe sọ pe ni kete ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni ọga ọlopaaa to wa ni agbegbe naa, Gabriel Fọlọrunshọ, ti ko awọn ọmọọṣẹ rẹ sodi lọ sibẹ, ti wọn si ri i pe alaafia jọba nibẹ.
Ṣugbọn ki wọn too debẹ ni wọn ti dana sun awọn ọkada naa. Awọn ọlọpaa yii ni wọn si doola ọkunrin to wa ọkada ọhun lọwọ awọn ọdọ ti wọn ti lu u lalubami, ti wọn si n mura ati dana sun un. Lẹyin eyi ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu lati doola ẹmi rẹ.

Leave a Reply