Nitori ti wọn dari alaisan lọ si ọsibitu aladaani, ijọba da dokita ati nọọsi duro nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori ti wọn dari awọn alaisan lọ sileewosan aladaani, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti da dokita kan ati nọọsi kan duro.

Alaga igbimọ to n mojuto eto ilera nipinlẹ naa, Dokita Gbọla Adetunji, lo kede igbesẹ naa nibi atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ” dokita ati nọọsi kan dari alaisan to yẹ ki wọn ṣiṣẹ abẹ fun lọ sileewosan aladaani, eyi to lodi si ofin ati ilana iṣẹ iṣegun oyinbo.
“M ọlẹbi awọn alaisan ti ọrọ yii kan ni wọn fẹsun yẹn to igbimọ eleto ilera leti, ti awọn igbimọ si pe awọn mejeeji fun iwadii.
“Lẹyin ti igbimọ to n ṣakoso eto ilera ipinlẹ yii ti ri i pe awọn eeyan wọnyi jẹbi ẹsun naa ni wọn fiya ọhun jẹ wọn”.
Nigba to n kilọ fawọn dokita ati nọọsi to n tapa si ofin ati ilana iṣẹ naa, Dokita Adetunji gboṣuba fun Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fun bo ṣe mu ayipada rere ba ẹka eto ilera.

Leave a Reply