Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un yii, ni ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ iṣejọba Gomina Abdulrahman AbdulRazaq, ti ileepo kan ti wọn n pe ni Fortunate, to wa lagbegbe Sango, niluu Ilọrin, pa lori ẹsun pe wọn de epo mọle, wọn o ta a.
Saaju ni gomina ipinlẹ Kwara, to tun jẹ alaga awọn gomina lorile-ede Naijiria, Abdulraman AbdulRazaq, ti kede pe eyikeyii alagbata epo to ba gbe epo pamọ ti ko ta a, ijọba yoo gba iwe-ẹri irufẹ ileepo bẹ lai boju wẹyin, ti gomina si yan awọn agbimọ ti yoo maa kiri ka gbogbo ilu Ilọrin, ati agbegbe rẹ lati mu awọn to ba tapa sofin. Gomina paṣẹ yii lẹyin ti iroyin kan an pe awọn ileepo kan ti gbe epo pamọ, ti wọn si n parọ pe awọn ko lepo nitori ọrọ ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu sọ lori owo iranwọ epo.
Ajọ yii, ẹka tipinlẹ Kwara, fọn sita niluu Ilọrin, wọn n ki ọpa bọ inu koto ti awọn elepo n japo si, ẹyi lo tu aṣiri awọn elepo ọhun.
Lẹyin ti ijọba ti ileepo yii tan ni gbogbo awọn ileepo to gbepo pamọ, ti wọn ni awọn ko ni epo bẹrẹ si i silẹkun ileepo wọn, ti wọn si bẹrẹ si i ta epo lọ ni pẹrẹu.