Nitori ti wọn fi i sahaamọ lọna aitọ, Olushọla wọ ijọba Kwara lọ sile-ẹjọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni Olusẹgun Olushọla aka (Sholyment), to maa n ta ko ijọba lori ayelujara wọ Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Kwara, agbẹjọro agba to tun jẹ kọmiṣanna lẹka eto idajọ nipinlẹ Kwara ati Anti gomina, Khairat, lọ sile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, fẹsun pe wọn fi i sahaamọ lọna aitọ, o si n beere fun ki wọn tu oun silẹ kiakia, ki wọn n tọrọ aforiji lọwọ oun ni gbangba. Bakan naa lo tun ni ki wọn  san igba miliọnu naira owo gba ma binu fun oun.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, fiwe pe Oluṣẹgun Olushola, aka ( Sholyment.) to jẹ ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oṣelu alatako PDP, nipinlẹ Kwara, ti wọn si fi i sahaamọ fẹsun pe o n sọrọ abuku si ijọba ipinlẹ Kwara, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, si tutọ soke foju gba a, wọn naka aleebu si Gomina Abdulrahman Abdulrasaq pe o fi Olushọla si ahamọ lọna ti ko bofin mu.

Ni bayii Olushọla ti wọ gbogbo awọn tọrọ kan lọ si ile-ẹjọ pe ki wọn tu oun silẹ lahaamọ ati pe lẹyin itusilẹ ọhun, wọn o gbọdọ mu oun mọ. Bakan naa lo ni ki wọn san owo gba ma binu ti ko din ni igba miliọnu kan naira, ki wọn si tọrọ aforiji ni gbangba.

Leave a Reply