Nitori ti wọn ko gba awọn ti ko sanwo ileewe laaye lati ṣedanwo, awọn akẹkọọ Poli Ọffa ṣewọde

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn akẹkọọ ileewe gbogbonise tijọba apapọ tilu Ọffa, nipinlẹ Kwara (Federal Polytechnic, Ọffa), ṣewọde latari pe wọn ni awọn alaṣẹ ileewe naa ko fun awọn ti ko ti i sanwo ileewe laaye lati ṣe idanwo ati awọn ẹsun miiran to fara pẹ ẹ.
Lati bii ọsẹ meji sẹyin ni awọn akẹkọọ naa ti n ṣe iwọde laaarin ilu Ọffa, ti wọn si tun lọ si aafin Ọlọfa, Ọba Mufutau Gbadamọsi, ti wọn rọ ọ pe ko da si ọrọ to n lọ laarin awọn akẹkọọ atawọn alaṣẹ ileewe naa.
Lara awọn ẹsun ti wọn ka si awọn alaṣẹ lọrun ni bi wọn ṣe ni ko saaye fun awọn ti ko sanwo ileewe lati jokoo fun idanwo, wọn ni ko sina, ko somi ni ni ilegbee awọn akẹkọọ, bakan naa ni wọn ni ki awọn akẹkọọ to wa ni ipele aṣekagba to ba fidi-rẹmi ninu awọn kọọsi kan maa waa tun un ṣe ni.
Awọn akẹkọọ naa sọ pe ki wọn gba awọn ti ko ti i sanwo ileewe laaye ki wọn ṣe idanwo, ki wọn si ma gbe esi jade titi ti wọn aa fi sanwo naa. Lasiko iwọde yii ni wọn ba ọkọ kan to jẹ ti olukọ wọn jẹ, ti wọn si di awọn ọkọ to n lọ si Oṣogbo lati Ọffa ati Ilọrin, lọwọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: