Nitori ti wọn lu mọto onimọto ta ni gbanjo, ijọba ranṣẹ pe ọga FRSC ipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Igbimọ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ lati ṣewadii iya to jẹ awọn eeyan lasiko ifẹhonu han ‘End SARS’ nipari ọdun to kọja (2020), ti ranṣẹ pe oludari ajọ eleto aabo oju popo, Federal Road Safety Corp (FRSC), Abilékọ Uche Chukwura, lati waa sọ tẹnu ẹ lori iwa ika ti wọn fi kan wọn.

Olukọ ileewe aladaani kan, Ọgbẹni Ayọdele Franscis Olutoye lo fẹsun kan ajọ FRSC níwájú igbimọ náà l’Ọjọbọ, Tọsidee to kọja, pe wọn fọwọ ọla gba oun loju.

Ninu awijare ẹ níwájú igbimọ ẹlẹni mẹ́wàá ọ̀hún, eyi ti Adájọ́-fẹ̀yìntì Badejokoo Adeniji, ti í ṣe Adajọ agba ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri jẹ alága fún, l’Ọgbẹni Olutoye ti sọ pé niṣe lawọn oṣiṣẹ ẹṣọ alaabo oju popo lù ọkọ ayọkẹlẹ ti oun fi n ṣẹṣẹ rin tà ni gbàǹjo.

Gẹgẹ bi Amofin J.B. Ọlaoye ti í ṣe agbẹjọro olùfisùn ṣe ṣàlàyé ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin wa lẹyin igbẹjọ naa, o ni “Wọn gbẹsẹ le ọkọ oníbàárà mi lai bofin mu ni.

“Lọjọ kẹrindinlogun, oṣù kin-in-ni, ọdun 2016, lawọn oṣiṣẹ FRSC mu Ọgbẹni Olutoye laduugbo Dugbe n’Ibadan.

“Lati Adamasingba lo ti n bọ, nibi to ti lọọ fi mọto já ọrẹ ẹ silẹ. O n pada lọ sọna Challenge ni wọn mu un, ti wọn sì gba mọto rẹ lọna ti ko boju mu.

“Ti awọn oṣiṣẹ FRSC to mu un bá fẹẹ tẹle ofin ati ilana iṣẹ wọn, o yẹ ki wọn fun un níwéè ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn kàkà kí wọn ṣe bẹẹ, owo abẹtẹlẹ ẹgbẹrun meji naira (N2000) ni wọn béèrè fún.

“Nitori pe o kọ láti san abẹtẹlẹ túú taosàn yẹn ni wọn ṣe gbe mọto rẹ lọ sí ọfiisi wọn.

“O mu ẹgbẹrun mẹfa naira (6,000) lọọ ba wọn nileeṣẹ wọn láti gbà mọto rẹ, wọn kò gba owo yẹn lọwọ ẹ̀. Igba yẹn ni wọn ṣẹṣẹ waa sọ fún ùn pe ìwé ọkọ rẹ̀ kò pẹ, ko lo bẹ́líìtì, ati pe ko ni iwe aṣẹ iwakọ. Wọn waa ni ko san ẹgbẹrun mẹ́ẹ̀ẹ́dogun Naira (N15,000) ko tóo lè gbà mọto rẹ.

“Nigba to lọọ san ẹgbẹrun mẹẹẹdogun naira yẹn ni won tun fẹ̀sun kan an pé o tun ni lati sanwo pe o ti pẹ́ jù ko too waa gba moto rẹ nitori ọkọ yẹn ti lo oṣu mẹfa lọdọ awọn. Wọn tun ni ko san ẹgbẹrun mejidinlaaadọta (N 48,000) naira.

“Bi ọrọ ba ri bayii, ànfààní wa fún eeyan láti kọwe bẹ̀bẹ̀ pe kí wọn fojú fo ẹsun ti wọn fi kan oluwa rẹ. Ìwé yii lo n gbiyanju lati kọ lọwọ to fi gbọ pe wọn ti lù ọkọ̀ òun ta ni gbàǹjo.

Ninu iwe kan ti àjọ FRSC kọ ranṣẹ sí igbimọ náà ni wọn ti fèsì pé ìdájọ kan ti awọn gba nile-ẹjọ lo fún àwọn laṣẹ lati lu ọkọ naa ta ni gbanjo, kì í ṣe pé àwọn deede lù aago le e lori.

Ṣugbọn ìgbimọ olugbẹjọ ọ̀hún, labẹ akoso Onídàájọ-Agba Adeniji, ti sọ pé kò dáa tó fun ajọ eleto aabo oju popo láti kọwe ranṣẹ sí igbimọ ti ìjọba ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ yii lati fèsì sí irú ẹsun bẹẹ.

Nigba to n sun ijokoo mi-in lori igbẹjọ yii siwaju di Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindilogun, oṣù kẹta, ọdun 2021 yii, igbimọ náà rọ Amofin O.J. Bamiṣaye ti í ṣe alákòóso ẹka ofin fún ajọ FRSC lati waa ṣoju àjọ naa nibi ijokoo ọhun, ki ànfààní le tubọ wa fún wọn dáadáa láti wí awijare wọn.

Nigba to n fesi sí ìbéèrè akọroyin wa lori ẹrọ ibanisọrọ, oludari àjọ FRSC sọ pé bó tilẹ jẹ pé ọrọ awọn laasigbo to ṣú yọ lasiko ifẹhonu han ti awọn ọdọ ṣe lati jẹ ki ijọba fopin sí ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale (SARS’) ni igbimọ ti ìjọba ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ yii wa fún, sibẹ, àjọ naa pọn igbimọ yii le lati fesi sí iwe ẹsun ti Ọgbẹni Olutoye kọ ta kò awọn níwájú wọn.

Ṣugbọn kò sọrọ nipa po boya oun maa ràn èèyàn waa ṣoju àjọ eleto aabo oju popo níwájú igbimọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, to n bọ lọhun-un ti igbẹjọ naa yóò máa tẹsiwaju tabi bẹẹ kọ.

Leave a Reply