Nitori ti wọn n gbe ohun ija oloro kiri lọna aitọ, adajọ sọ ọmọ ẹgbẹ okunkun meji sẹwọn n’llọrin

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni adajọ sọ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meji, Sulyman Bankọle ati Balogun Ibrahim, sọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu Ilọrin, fẹsun pe wọn n gbe awọn ohun ija oloro kiri lọna aitọ.

 

 

Ileeṣẹ ọlọpaa lo wọ afurasi mejeeji lọ si ile-ẹjọ fẹsun pe wọn nj gbe awọn ohun ija oloro kiri lọna aitọ, wọn ni agbegbe Popo-Igbọnna, niluu Ilọrin, lọwọ ti tẹ wọn, nibi ti wọn fara pamọ si. Lara awọn ohun ti wọn ba lọwọ wọn ni ibọn kan, apoti aake kan, ọbẹ kan ati ọpọlọpọ igbo.

 

 

Agbefọba, Zacchaeus Folorunshọ, sọ fun kootu pe ko fi awọn afurasi naa si ahamọ titi ti wọn yoo gba imọran lẹka eto idajọ lori wọn,nitori pe ileeṣẹ ọlọpaa ti pari iwadii wọn.

Onidaajọ Ibrahim Dasuki pasẹ pe ki wọn sọ awọn afurasi mejeeji sọgba ẹwọn Oke-Kura, o sun igbẹjọ si ọjọ kẹwaa, osu Kẹsan-an, ọdun 2022.

 

Leave a Reply