Nitori ti wọn n lu araalu ni jibiti, ileeṣẹ DPR ti ile-epo marun-un pa ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Nitori bi wọn ṣe n ta epo ju iye tijọba fọwọ si, ileeṣẹ to n mojuto ọrọ tita epo bẹntiroolu lorilẹ-ede Naijiria, Department of Petroleum Resources (DPR), ti ti ile-epo marun-un pa niluu Ilọrin.

Awọn ile-epo ọhun ni DPR tun fẹsun kan ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe epo ti wọn tun n ta fun araalu ko pe.

Ọga agba DPR nipinlẹ Kwara, Onimọ-ẹrọ Sule Yusuf, ṣalaye pe ile-epo marundinlogoji lawọn lọ kaakiri lati yẹ wo. O ni ijọba ko lero ati fowo kun owo-epo, bẹẹ si ni ko si ọwọn epo bẹntiroolu, nitori naa, kawọn araalu ma foya tabi maa ra epo pamọ.

Yusuf ni DPR ṣakiyesi pe awọn alagbata epo kan n funra wọn fi owo kun owo-epo lati maa fi ni araalu lara.

O ni meji lara awọn ile-epo to n ta ju iye tijọba fọwọ si sa lọ lasiko tawọn oṣiṣẹ DPR n lọ kaakiri, nitori pe wọn mọ pe ohun ti awọn n ṣe lodi sofin.

O tẹsiwaju pe awọn ile itaja naa yoo ṣi wa ni titi pa, lẹyin ti wọn ba sanwo itanran, ti wọn si tẹle aṣẹ ijọba ni yoo too di ṣiṣi.

Yusuf ni, “Ijọba ko fowo kun epo o. Bi araalu ba ri ile itaja kankan to n ta jala epo bẹntiroolu kan ju naira marundinlaaadọsan-an, #165, ki wọn fi to wa leti. A maa de ile itaja epo naa, a si maa ri i pe wọn fi dandan pada si iye tijọba fọwọ si.”

O gba awọn to ni ile-epo nimọran lati maa tẹle aṣẹ ijọba, ki wọn si ma yan araalu jẹ nipa jijẹ ere ajẹpajude.

 

Leave a Reply