Nitori Tinubu, awọn ọmọ ita da ibọn bolẹ n’Ilẹ-Oluji, lawọn eeyan ba n sa kijokijo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe lawọn eeyan n sa kijokijo pẹlu ibẹru nigba ti wọn n gbọ iro ibọn to n ro lakọlakọ laarin igboro Ilẹ-Oluji to jẹ ibujokoo ijọba ibilẹ Ilẹ-Oliji /Oke-Igbo, lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, lojiji lawọn eeyan ilu ọhun deedee n gbọ irọ ibọn ọhun to n dun leralera lagbegbe kan ti wọn n pe ni Roundabout, nitosi aafin Jẹgun ti Ilẹ-Oluji, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ naa.
Iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo da jinnijinni to kọja afẹnusọ sara awọn araalu, paapaa awọn to n gbe lagbegbe ibi ti wọn ti sina ibọn bolẹ.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ ninu alaye ti araalu kan ta a forukọ bo laṣiiri ṣe fun wa nipa iṣẹlẹ ọhun pe bo tilẹ jẹ pe ilẹ ko ti i fi bẹẹ ṣu daadaa lasiko naa, kiakia lawọn eeyan ti sa wọ ile wọn, ti olukuluku si tilẹkun mọri nitori ibẹru.

Ọpọ awọn tọrọ naa ka mọ igboro lo ni wọn fẹsẹ rin pada sile wọn nigba ti wọn ko ri ọkada tabi ọkọ gbe wọn.

Nibi ti iṣẹlẹ ọhun ba awọn eeyan lẹru de, ọpọ awọn ọlọkada ni wọn n kọ lu ara wọn nibi ti wọn ti n sa asala fun ẹmi wọn, ti gbogbo nnkan si daru laarin asiko naa.
Lẹyin-o-rẹyin lo ni awọn ṣẹṣẹ n gbọ pe awọn eeyan kan ni wọn n yinbọn lati fi ayọ wọn han lori bi wọn ṣe kede orukọ Bọla Tinubu gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ APC ti wọn di l’Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, mọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ẹlomi-in to tun ba wa sọrọ ni ki i ṣe asiko yii ti ẹru iṣekupani to waye ninu ijọ Katoliiki Francis Mimọ, niluu Ọwọ, si wa lara awọn eeyan ipinlẹ Ondo lo yẹ kawọn alatilẹyin ẹgbẹ APC maa yinbọn lati fi ṣajọyọ jijawe olubori ẹnikẹni.

Ọkunrin to ba wa sọrọ kẹyin ni o yẹ kawọn agbofinro ati Jẹgun ti Ilẹ-Oluji tete gbe igbesẹ lori ọrọ awọn janduku oloṣelu ọhun ko too pẹ ju, nitori pe iyẹn ki i ṣe igba akọkọ ti wọn n dẹru bawọn eeyan.

Leave a Reply