Faith Adebọla
Ko jọ pe aawọ to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, yoo pari bọrọ, tori kaka kewe agbọn ija naa dẹ, niṣe lo n le si i, latari bi Gomina ipinlẹ Rivers, Amofin Nyesom Wike, ṣe tun wọle ipade atilẹkun-mọri-ṣe mi-in niluu London, lorileede United Kingdom.
Lọtẹ yii, Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ati Akọwe apapọ fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, ni Wọn ṣepade pẹlu Wike lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan-an, ta a wa yii.
Awọn ti wọn tun wa nibi ipade naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, ati Gomina ipinlẹ Abia, Dokita Okezie Ikpeazu.
Bo tilẹ jẹ pe Ikpeazu ti la a mọlẹ fawọn ololufẹ rẹ ko too wọ baaluu pe ni toun o, oun o ni i fẹgbẹ PDP silẹ lasiko yii rara, o ni idi toun fi wa lẹyin Wike ko kọja bi wọn ṣe maa ri i pe ẹya Igbo rọwọ mu ninu ijọba to n bọ, ati bi omi tuntun yoo ṣe ru ninu ẹgbẹ naa, t’ẹja tuntun yoo si wọ ọ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, to lọ yii lawọn gomina PDP naa kuro ni Naijiria lọ siluu London, Gomina Ṣeyi Makinde si ti wa lọhun-un tẹlẹ, tori ilu eebo to ti lo eyi to pọ ju lọ ninu isinmi oṣu kan to gba, o si ti faṣẹ le Igbakeji rẹ tuntun, Amofin Abdulroheem Bayọ Lawal, lọwọ, gẹgẹ bii adele.
Alami kan to sọrọ nipa ipade bookẹlẹ wọn ọhun sọ pe lajori ijiroro wọn da lori bi Wike atawọn tiẹ yoo ṣe ṣiṣẹ fun ẹgbẹ APC ati oludije rẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lasiko eto idibo gbogbogboo to n bọ ni 2023 ọhun, bi wọn o ba tiẹ kuro ni PDP ti wọn wa.
Ṣaaju asiko yii, ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, ni oludije funpo aarẹ ni APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ṣe ipade bonkẹlẹ kan pẹlu Wike, lati wa atilẹyin rẹ atawọn eeyan ipinlẹ Rivers. Ẹyin naa ni Atiku ati Peter Obi, oludije lẹgbẹ Labour Party lọọ ri Wike, pẹlu Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ.
A tun gbọ pe, yatọ si ijiroro pẹlu Fayẹmi ati Omiṣore, Wike atawọn ọrẹ ẹ tun fori kori lori ọna ti wọn yoo tọ ki ipade igbimọ alakooso ẹgbẹ naa, National Executive Committee (NEC), too waye, nibi ti ireti wa pe wọn yoo ti fẹnu ọrọ jona lori iyọnipo Alaga apapọ ẹgbẹ wọn, Iyorchia Ayu, boya ko kuro nipo tabi ko ṣi maa ba iṣẹ rẹ lọ. Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe ipade NEC naa yoo waye l’Abuja.
Ọrọ Alaga ẹgbẹ ti fẹẹ di mi-in fun oludije funpo aarẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar, latari bawọn agbaagba ṣe n kọminu si didakẹ ti Atiku dakẹ lori erongba lati yọ Ayu nipo. Wọn ni awuyewuye ọrọ yii lo jẹ idi pataki ti ipade awọn gomina PDP to yẹ ko ti waye ko ṣe ti i waye, wọn ni Alaga awọn gomina PDP, Aminu Tambuwal, ti i ṣe gomina ipinlẹ Sokoto, wa lara awọn to ṣẹ Wike leegun ẹyin lasiko eto idibo abẹle wọn, eyi to jẹ ki Wike padanu sọwọ Atiku.
Tẹ o ba gbagbe, ọpọ awuyewuye lo n lọ lori ipo Ayu, bawọn gomina kan ṣe kin Wike lẹyin pe iyọnipo Alaga naa lo daa, tori ọpọ ipo gidi ninu ẹgbẹ oṣelu naa lo ti bọ siha Ariwa, awọn ti Guusu naa si fẹ kawọn ipo pataki bii Alaga ẹgbẹ pada siha Guusu, yatọ si ti igbakeji oludije funpo aarẹ ti wọn yan Ifeanyi Okowa si. Ọrọ naa ti le debi ti Ayu ati Wike ti n sọko ọrọ, ti wọn si n powe mọ ara wọn.
Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ni wọn n reti ki Atiku sọrọ lori awuyewuye naa.