Nitori Tinubu, MC Oluọmọ atawọn ọmọ ẹ ya si titi, ko sọna lati Eko d’Oṣodi

Faith Adebọla, Eko 

Pitimu lawọn ero ya di ọna marosẹ to lọ lati Surulere wa si Oṣodi lowurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹwaa yii, ko sọna rara fun ọkọ, kẹkẹ Marwa tabi ọkada kankan lati kọja, latari irin ayẹsi akanṣe kan ti olori igbimọ to n ṣakoso awọn gareeji ọkọ l’Ekoo, Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, ṣeto rẹ. O loun atawọn eeyan miliọnu marun-un fẹẹ rin lati yipo Eko tori oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati oludije funpo gomina Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu.

Lati afẹmọju ọjọ Sannde ọhun, awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto, lati origun mẹrẹẹrin Eko, ti n rọ de si papa iṣere Teslim ati ti apapọ ilẹ wa, National Stadium, to wa lagbegbe Surulere ọhun.

Lẹlẹgbẹjẹgbẹ, ọlọgbajọgba ni wọn n de, kaluku wọn ni wọn wọṣọ ẹgbẹjọda, ọpọ si de fila ti wọn ya ami to maa n wa lara fila Tinubu sori, bẹẹ ni wọn n kọrin ayẹsi ati orin owe loriṣiiriṣii.

Yatọ sawọn onimọto, awọn gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa naa ko gbẹyin, lara awọn to tete de sibi eto naa naa ni awọn ti Saheed Balogun ko sodi, bii Fausat Balogun tawọn eeyan mọ si Ṣajẹ ti o lọgaa, Ẹbun Oloyede ti wọn tun n pe ni Ọlaiya Igwe ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn oṣere tiata elede eebo naa wa pẹlu, kinni ọhun ko si yatọ si ayẹyẹ kanifa nla ti wọn maa n ṣe.

Amọ lati afẹmọju ọhun ni ojo ti n rọ, inu ojo naa lawọn ero ọhun n de si, kaluku wọn lo n wa lailọọnu ti wọn maa fi tọju foonu ati awọn nnkan ti omi le bajẹ to wa lara wọn si, wọn ko si kuro ninu ejiwọwọ ọhun, bẹẹ ni wọn ṣe n rin lati Surulere wa sọna Oṣodi, wọn gba ọna Funṣọ Williams jade si Bọlade, bi wọn ṣe n lulu, ni wọn n darin ọlọkan-o-jọkan, wọn n gbe e, wọn si n n jo ajorin lọ, gbogbo orin ọhun ko kọja pe Tinubu ati Shettima lo maa di aarẹ ati igbakeji ẹ lọdun to n bọ, Sanwo-Olu si gbọdọ ṣe saa keji l’Ekoo.

Bakan naa lawọn agbofinro ati ẹṣọ alaabo pe biba sibi ayẹyẹ ọhun, latori ọlọpaa si sifu difẹnsi, atawọn ẹṣọ Neighbourhood Eko, awọn ẹṣọ alaabo aladaani ko gbẹyin.

MC Oluọmọ to ti kọkọ sọ pe oun ṣi fawọ ro lori idije naa, kede lọjọ Satide to ṣaaju pe idije ọhun maa tẹsiwaju, o lawọn agbaagba ati ijọba Eko ti fọwọ si i, ati pe iyalayaa ayẹyẹ atilẹyin leyi tawọn ṣe yii, o ni niṣe lawọn maa ti Eko pa fun Tinubu ati Sanwo-Olu.

‘A fẹ lati ṣafihan atilẹyin wa, bi a ṣe pọ to, ba a ṣe lero lẹyin to, kawọn eeyan le mọ pe ki i ṣe ṣereṣere rara, awọn oludije lẹgbẹ oṣelu APC maa wọle lai sọsẹ lọdun to n bọ ni’, gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply