Nitori to da foonu ero to ri pada, ẹgbẹ awakọ fun dẹrẹba lẹbun ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Latari pe o ri foonu Arabinrin Khadijat Eyitanwa Lawal, to si da a pada fun un, ẹgbẹ awakọ NURTW, ẹka tilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara,

ti fun awakọ takisi kan, Moshood Ayinde, lẹbun ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii.

ALAROYE gbọ pe Khadijat wọ takisi Ayinde lati Agbo-oba lọ si Irewọlede, lẹyin to sọkalẹ tan ni awakọ naa ri foonu rẹ ninu ọkọ, ni kete ti wọn pe foonu ọhun ni Ayinde gbe e, to si da foonu naa pada fun ẹni to ni i. Lati le ṣe koriya fun un pẹlu iwa ọmọluabi to hu, Alaga ẹgbẹ awakọ NURTW niluu Ilọrin, Alaaji Ariwoola, fun un ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira gẹgẹ bii ẹbun iwe rere rẹ.

Ninu ọrọ dẹrẹba naa, o ni ti oun ba gbe foonu ẹni ẹlẹni ti oun ba ta a, oun yoo na owo ẹ tan, ti oun ba si n lo o, ẹni to ni foonu naa yoo wa ninu ibanujẹ, foonu naa yoo si pada bajẹ lọjọ kan ni, idi niyi ti oun fi da a pada. Alaga ẹgbẹ naa waa yin in lawo pẹlu bo ṣe tẹle ofin ati ilana ẹgbẹ nipa dida awọn ẹru ẹlẹru ti wọn ba ri he pada.

 

Ninu ọrọ Arabinrin Eyitanwa, o ni oṣi ko ni ki eniyan maa huwa jibiti, igbesẹ ti Ayinde gbe yii n fi iwa ọmọluabi ti ko ṣee fọwọ rọ danu lawujọ han, ti eyi si fi han pe ireti wa pe orile-ede yii yoo pada dara.

Leave a Reply