Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, nile-ẹjọ Majisireeti kan ni ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti ju baba ẹni ọdun marundinlogoji, Oyefẹsọ Saheed, si ahamọ fẹsun pe o fi ọmọdebinrin rẹ ti ko ju ọmọ ọdun mejila lọ, fun Ismail Lawal, ẹni ọdun mejilelọgbọn gẹgẹ bii iyawo.
Ẹgbẹ agbẹjoro obinrin lagbaaye (FIDA), ẹka ti ipinlẹ Kwara, ni wọn mu ẹjọ naa lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Adewọle, niluu Ilọrin latọwọ Arabinrin Aishat Temeem, lẹyin to gba ipe latọdọ ọga ileewe ọmọ ti wọn fi fọkọ ọhun. Oju-ẹṣẹ ni wọn lọọ mu baba ọmọbinrin naa, ti wọn si tun wọ ọ lọ siwaju Adajọ Shade Lawal, nile-ẹjọ Majisreeti kan to wa niluu Ilọrin.
Lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo fun ọmọ ọhun, iwadii fi han pe wọn ti jabaale rẹ.
ALAROYE gbọ pe (laptop Hp) ni baba ọmọ naa gba gẹgẹ bii owo-ori ọmọ rẹ lọwọ ọkọ to fi i fun. Ni bayii wọn ti mu ọkọ iyawo, toun naa si ti wa ni ahamọ.
Ẹsun meji ọtọọtọ ti ile-ẹjọ fi kan wọn ni ifọmọde lọkọ ati ibanilopọ lọna aitọ, eyi to ta ko ẹtọ ọmọde. Eyi lo mu ki Agbefọba, Akinjide, rọ ile-ẹjọ pe ko fi baba ọmọ ati ọkunrin to n pe ara ni ọkọ si ahamọ.
Onidaajọ Shade ti ni ki awọn afurasi mejeeji maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn, o waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun yii.