Nitori to le maaluu kuro ninu oko irẹsi rẹ, Fulani ge ọwọ agbẹ ja bọ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọṣẹ yii, ni Fulani darandaran kan ge Ọgbẹni Saheed Zakariyau to jẹ agbẹ ladaa lọwọ ọtun lagbegbe Bindofu, Lafiagi, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe Ọgbẹni Saheed mu ẹsun lọ sọdọ ajọ ẹṣọ alaabo (NSCDC), to wa ni Lafiagi, awọn Fulani darandaran ti ge oun ni ada lọwọ latari pe awọn n le maaluu kuro ni oko irẹsi awọn ti wọn da maaluu si.

Saheed salaye pe ni nnkan bii aago mẹsan-an owurọ ni oun pẹlu ẹlẹgbẹ oun de oko, kete tawọn debẹ lawọn ba awọn maaluu ti wọn n jẹ oko irẹsi awọn, ti awọn Fulani si duro ti wọn, bi awọn ṣe n gbinyanju lati le wọn danu ni Fulani kan fa ada yọ, to si fi ge oun lọwọ.

Alukoro ajọ naa ni Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, ti waa fi awọn agbẹ naa lọkan balẹ pe awọn yoo ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa, awọn yoo si fi oju aṣebi han.

Leave a Reply