Nitori to le wọn kuro ninu oko ọga rẹ, Fulani darandaran gun Akilẹṣọ pa ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọkunrin kan, Akilẹṣhọ Attah, pade iku ojiji nigba ti Fulani darandaran, Manu Usman, gun un lọbẹ pa nitori bo ṣe n le awọn maalu rẹ kuro ninu oko ọga ẹ niluu Gwanara, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara.

Lọjọ iṣẹlẹ buruku naa, ori oko agbado ọga rẹ torukọ rẹ n jẹ Agboisa Comuni ni Akilẹṣhọ ti ba Usman atawọn akẹgbẹ rẹ mẹta mi-in pẹlu awọn maalu wọn ti wọn n jẹko. Biyẹn ṣe koju ẹ ni darandaran naa fa ọbẹ yọ si i.

Nibi ti Akilẹṣhọ ti n sa lọ ni Usman ti gba tẹle e, bo ṣe kan an lara lo gbe ọbẹ le e lọrun laimọye igba, to si gun un ṣakaṣaka.

Akọsilẹ ọlọpaa sọ pe ilewosan kan ti wọn gbe ọkunrin naa lọ lo dakẹ si, ṣugbọn ọwọ pada tẹ Usman lagọọ Fulani Wadata, lọna Gwanara.

Agbẹjọro ijọba,  Zacheous Fọlọrunṣhọ, ni ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan olujẹjọ naa, nitori idi eyi, ko lẹtọọ si beeli. O rọ ile-ẹjọ lati gbe e satimọle.

Adajọ Abdulraheem Bello ni ki wọn gbe afurasi sahaamọ ọgba ẹwọn titi di ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun 2021.

Leave a Reply