Nitori to lu jibiti lori ẹrọ ayelujara, adajọ sọ agunbanirọ sẹwọn ọdun meji n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ti sọ agunbanirọ to n sin ilẹ baba rẹ niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, Caleb Oyeyẹmi, sẹwọn ọdun meji fun ẹsun jibiti ibalopọ lori ayelujara.

Onidaajọ Adenikẹ Akinpẹlu ni ki ọmọkùnrin naa lọwọ ṣẹwọn ọdun meji latari pe o jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an pe  o lu arakunrin kan Wilson, ni jibiti ibalopọ latori ayelujara.

Oyeyẹmi jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun, o si jẹ ọmọ bibi Odo-Ọwa, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara, ajọ EFCC fi panpẹ ofin gbe e lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹta, ọdun ta a wa yii. Ajọ naa ni Oyeyẹmi gbe foto obinrin asẹwo ilu oyinbo sori ayelujara, o si dibọn pe iṣẹ aṣẹwo loun yan laayo, o si gba owo ti ko din ni ẹgbẹ̀rún lona ọgọrun-un kan dọla ($100), lọwọ Wilson gẹgẹ bii owo ti wọn o fi jọ ni ibagbepọ, ṣugbọn ọwọ palaba rẹ pada ṣegi, o si jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Onidaajọ Akinpẹlu ni gbogbo atotonu ati ẹbẹ onibaara rẹ ni oun gbọ ṣugbọn bi ile-ẹjọ ba tu Oyeyẹmi silẹ, bii ẹni pe a n faaye gba iwa ọdaran ni, fun idi eyi, o ni ko san ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba naira (# 200,000) owo itanran, ki ijọba apapọ si gbẹsẹ le ẹrọ ibanisọrọ to mu wa si ajọ EFCC ati ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrin naira (#80,000) to wa ninu asunwọn rẹ, ko ṣẹṣẹ waa lọọ lo ọdun meji lọgba ẹwọn.

Leave a Reply