Nitori to lu jibiti lori ẹrọ ayelujara, adajọ sọ Gideon sẹwọn ọgbọn ọjọ n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, nile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara  Ọkẹ Gedeon, ẹni ogun ọdun, sẹwọn ọgbọn ọjọ n’Ilọrin, fun ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ  ayelujara.

Onidaajọ Mahmood Abdulgafar ni ki ọmọkunrin naa lọọ ṣẹwọn ọgbọn ọjọ, latari pe o jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an pe o n lu awọn eniyan ni oniruuru jibiti lori ayelujara.

Gideon ni ajọ EFCC, ẹka tilu Ilọrin, fi panpẹ ofin gbe lọjọ kẹrin, oṣu karun-un, ọdun yii, niluu Ilọrin. Ajọ naa ni o gbe fọto obinrin  sori ayelujara, o si dibọn pe obinrin loun lati fi gba awọn ọkunrin loju, ṣugbọn ọwọ palaba rẹ pada ṣegi, o si jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọjọ Ẹti, Furidee, ọṣẹ yii, ni wọn wọ Gideon lọ sile-ẹjọ  fun ẹsun meji  ọtọọtọ, ṣugbọn ọdaran naa ko jiyan, o ni loootọ loun jẹbi ẹsun mejeeji ọhun.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe Gideon n pe ara rẹ  ni ( Jẹnna Cherry), to fi n lu awọn eniyan ni jibiti laarin oṣu kẹjọ, ọdun 2020, si oṣu kẹsan-an, ọdun 2020, niluu Ilọrin. O ti gba owo ti ko din ni aadọjọ owo dọla pẹlu ẹbun lọwọ okunrin kan to n jẹ Bradley Miller, to si parọ pe Jerry ni orukọ oun n jẹ, ọmọbinrin lati ilu Las Vegas, ni ilẹ Amẹrika, ni oun to si jẹ pe irọ ni.

Onidaajọ Abdulgafar ni ki ẹrọ ibanisọrọ (iPhone 6) to n lo, ati (laptop) to fi n ṣiṣẹ aburu naa di ti ijọba apapọ, ko si lọọ fẹwọn ọgbọn jura.

Leave a Reply

%d bloggers like this: