Nitori to n jade pẹlu ọrẹkunrin mi-in, Fatai atawọn ọrẹ ẹ lu ọrẹbinrin rẹ lalubami ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ni ọdọmọkunrin kan, Fatai, wa bayii. Niṣe lo gbimọ-pọ pẹlu awọn ọrẹ ẹ, wọn bọ ọrẹbinrin rẹ, Adukẹ, sihooho, wọn si lu u bii bẹmbẹ nitori ẹsun pe o n fẹ ọkunrin miiran.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, SP Ajayi Okasanmi, sọ pe ọwọ ti ba ọmọkunrin to gbimọ pọ pẹlu awọn ọrẹ ẹ, ti wọn si lu ọrẹbinrin rẹ, Adukẹ, lalubami, lẹyin ti wọn bọ ọ sihooho tan.
O tẹsiwaju pe ṣe ni fọnran fidio naa gba ori ayelujara, nibi ti awọn ọrẹ Fatai ti mu Adukẹ lọwọ, ti awọn kan si fa a lẹsẹ, wọn bọ gbogbo aṣọ rẹ silẹ, ti wọn si n to ẹgba si i ni pata fẹsun pe o tun n fẹ ọkunrin miiran.
Ọkasanmi ni Fatai ti wa ni ahamọ bayii, ti iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa. Lẹyin iwadii lo ni awọn eeyan naa yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply