Nitori tọkọ-tiyawo ti wọn ji gbe, awọn eeyan fẹhonu han l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ni kutukutu owurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn ajinigbe tun ji ọkọ atiyawo, oluṣọ aguntan kan ati awọn eeyan meji miiran gbe laduugbo Gosheni, Ajebandele, niluu Ado-Ekiti.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọsẹ mẹta ti wọn ji ọkunrin kan gbe laduugbo naa.

Eyi lo fa a tawọn ọdọ atawọn olugbe adugbo naa ṣe rọ jade si oju popo, ti wọn si n fẹhonu han lori ijinigbe to n waye leralera lagbegbe naa.

Awọn olufẹhonu han naa ti wọn to bii ọgọrun-un ni wọn gbe igi di oju ọna to lọ lati ilu Ado-Ekiti si Ikẹrẹ-Ekiti lati nnkan bii aago meje aarọ, ti wọn ko si jẹ ki mọto kankan kọja tabi ki awọn ọlọja maa ba ka-ta-ka-ra wọn lọ.

ALAROYE gbọ pe awọn agbebọn ọhun ya wọ adugbo na pẹlu ọkada, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke.

Lasiko naa ni wọn ji ọkọ atiyawo kan ti wọn n jẹ Falọmọ ati oluṣọaguntan kan.

Ibọn AK-47 la gbọ pe wọn gbe dani, ti wọn si bẹrẹ si i yin in soke bi wọn ṣe wọ adugbo naa ti wọn fi ko ọkọ atiyawo yii ni ẹnu ọna ile wọn.

Bi wọn ṣe gbe wọn tan ni wọn tun ri oluṣọagutan naa, ni wọn ba tun fi agbara gbe oun naa lori ọkada ti wọn gbe wa. Bakan naa ni wọn tun ri awọn ọkunrin meji kan bi wọn ṣe n jade kuro ninu adugbo naa, ti wọn si tun gbe awọn naa.

Bi wọn ṣe n lọ ni wọn yinbọn soke, ti gbogbo awọn to wa ni adugbo naa si n sa kijokijo.

Lẹyin iṣẹju diẹ ti awọn ajinigbe ọhun ti lọ tan la gbọ pe awọn ọlọpaa to wa ni teṣan Ọlọgẹdẹ ti wọn pe ṣẹṣẹ debi iṣẹlẹ ọhun.

Awọn olufẹhonu han naa ti wọn gbe akọle oriṣiiriṣii lọwọ sọ pe eto aabo ti mẹhẹ lagbegbe naa. Wọn waa ke si ijọba ipinlẹ Ekiti atawọn ẹṣọ agbofinro pe ki wọn ran awọn olugbe agbegbe naa lọwọ, ki eto aabo to gbopọn le wa ni adugbo naa.

Iwọde naa da sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ silẹ, niṣe lawọn ọlọpaa si n parọwa fawọn eeyan naa pe ki wọn na suuru si i.

Alaga adugbo Goshen, nibi ti ijinigbe yii ti waye, Ọgbẹni Samuel Fasua, sọ pe iwọde naa waye lati pe awọn ẹṣọ alaabo ati ijọba ipinlẹ Ekiti si akiyesi lori iwa ijinigbe to n waye leralera laduugbo naa.

” Iyawo ti wọn ji gbe naa lo gbe ọkọ rẹ to jẹ olukọ nileewe girama kan de ile pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti awọn ajinigbe naa si tẹle e lati ita. Bo ṣe de ẹnu ọna ile rẹ ni wọn bẹrẹ si i yinbọn soke.

Leave a Reply