Nitori wahala awọn Fulani darandaran nilẹ Yoruba, Gani Adams kọwe s’ajọ agbaye

Faith Adebọla

Latari bi wahala awọn Fulani darandaran to n fẹmi ṣofo nilẹ Yoruba ati kaakiri orileede Naijiria ṣe n peleke si i, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba ati olori ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC, Iba Gani Adams, ti kọ lẹta sawọn ajọ agbaye, awọn orileede nla l’Afrika, pe ki wọn ma ṣe fọwọ lẹran lori ọrọ Naijiria lasiko yii, ki wọn ba wa da si i, tori ewu nla lo n kanlẹkun bayii.

Lẹta naa, to pe akọle rẹ ni: “A fẹẹ da bawọn Fulani darandaran ṣe n paayan nipakupa duro nilẹ Yoruba kia,” lo kọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, oun funra rẹ lo si buwọ lu u, gẹgẹ bii Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba ati aṣaaju ẹya naa.

Ajọ agbaye mẹrin ọtọọtọ ni Gani Adams ko lẹta ọhun si, awọn ajọ naa ni Akọwe agba ajọ Iṣọkan Agbaye, United Nations (UN), alaga ajọ iṣọkan ilẹ Afrika, African Union (AU), Akọwe agba fun ajọ orileede ilẹ Yuroopu, iyẹn European Union (EU) ati ajọ awọn orileede Iwọ-Oorun Africa ti wọn n ṣowo papọ, Economic Community for West African States (ECOWAS).

Yatọ si awọn ajọ agbaye wọnyi, Adams tun dari lẹta to fi n kegbare ọhun si Akọwe apapọ fun orileede Amẹrika, Secretary of State for United States of America ati akọwe ọrọ okeere lorileede Gẹẹsi, British Foreign Secretary.

Gani Adams tun kọwe ṣọwọ sawọn aṣoju orileede Germany, Italy, Sweden, Mexico, Spain, Russia, Holland, South Africa, Japan, Canada, Ghana, Togo, Cameroun, Chad, Benin Republic ati awọn mi-in.

Ninu lẹta ọhun, Aarẹ sọ pe iṣoro aabo to n ba orileede Naijiria finra lọwọ yii ti kọja nnkan tawọn orileede agbaye le maa wo niran tori ọrọ naa ti n mu ilẹ wa lomi gidi, o si ti fẹẹ fọ orileede naa si wẹwẹ.

O ni ẹya Yoruba ti ki i ja lawọn Fulani ti orungbẹ ẹjẹ n gbẹ ti n han leemọ bayii, wọn si ti yipo ilẹ Yoruba, wọn ti n ṣọṣẹ loriṣiiriṣii.

Bakan naa lo naka aleebu si ijọba orileede Naijiria ninu lẹta rẹ, o ni niṣe nijọba to wa lode yii tubọ n bu epo si ina ọrọ ọhun, pẹlu bi wọn ṣe n fọwọ ra ẹya Fulani lori lati maa ṣakọlu sawọn ẹya ati agbegbe to ku.

O ni ojuṣe awọn orileede agbaye ni lati da si i tọrọ ba ri bayii, paapaa bo ṣe jẹ pe ọpọ awọn orileede ati ajọ wọnyi ni wọn ni okoowo kan tabi omi-in ni Naijiria, ki wọn si ranti pe orileede adulawọ to tobi ju lọ lagbaaye lo n luwẹẹ ninu iṣoro yii.

Gani Adams tọka si bawọn Fulani apaayan ṣe ya bo ilu Igangan, lagbegbe ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ kẹfa, oṣu kẹfa yii, ti wọn si ṣakọlu sawọn eeyan laajin oru, ti wọn pa wọn nipakupa. O ni iṣẹlẹ yii ti sun Yoruba kan ogiri wayi, oun si parọwa pe ki awọn orileede agbaye ma sọ pawọn ko gbọ tabi ri ohun to n ṣẹlẹ, tori ewu nla lo n rọ dẹdẹ lori iṣọkan Naijiria bayii.

Nipari lẹta rẹ, o ni: “O han kedere pe apa ti kun ijọba apapọ lori ọrọ aabo yii, ọwọ ijọba naa ko si ran ojuṣe wọn lati daabo bo ẹmi ati dukia nilẹ wa mọ. Naijiria ti wa ni ọgẹgẹrẹ, niṣe lo n yi gbirigbiri bii bọọlu lọ soko iparun ati ifọsiwẹwẹ. Ko si ọrọ ọgbọn ati amọran agba to ṣiṣẹ mọ bayii o.”

Leave a Reply