Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ iṣejọba Gomina Abdulraman AbdulRazaq, ti ṣe ipade pẹlu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ Karun-un, oṣu Kẹfa yii, o din iṣẹ wọn ku si ọjọ mẹta pere laarin ọsẹ.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe gomina AbdulRazaq, Murtala Ayọyebi, fi sita niluu Ilọrin, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe olori awọn oṣiṣẹ ni Kwara, Arabinrin Susan Oluwọle, ti dari gbogbo awọn olori lẹka ileeṣẹ ijọba kọọkan lati din ọjọ tawọn oṣiṣẹ wọn yoo fi maa lọ sibi iṣẹ ku. O ni ijọba Kwara gbe igbesẹ yii fun igba diẹ latari ọwọngogo owo ọkọ to waye lẹyin tijọba apapọ yọ owo iranwọ lori epo. O ni eyi yoo din wahala ku lọrun awọn oṣiṣẹ tori pe irọrun igi ni irọrun ẹyẹ.
O rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ni Kwara, lati ma ṣe ṣi anfaani ti ijọba fun wọn lo, tori pe ijọba yoo maa ṣọ wọn loju, sọ wọn lẹsẹ.