Monisọla Saka
Awọn ọmọ bibi ipinlẹ Kogi ti wọn n ṣe atipo lorilẹ-ede UK, labẹ asia ẹgbẹ ti wọn pe ni “Concerned Citizens of Kogi State”, ti ṣewọde ifẹhonu han wọọrọwọ lọjọ Aje, Mọnnde, ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, pẹlu erongba ati bẹ ijọba pe ki wọn fi panpẹ ofin gbe gomina Yahya Bello, ki wọn si ṣewadii finnifinni nipa ọkunrin to ṣẹṣẹ fipo silẹ nipinlẹ naa, ati gbogbo awọn eeyan ẹ fun ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.
Ẹni to ṣaaju iwọde naa, Ọgbẹni Cyril Akubo, ati Akọwe agba ẹgbẹ wọn, Amofin Samuel Promise, pẹlu gbogbo awọn olufẹhohu han yooku ni wọn gbe oriṣiiriṣii paali ti wọn kọ ohun ẹdun ọkan wọn si dani niwaju ileeṣẹ ilẹ Naijiria to wa niluu London.
Wọn ni o dun mọ awọn pe ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission, (EFCC) ti jẹwọ pe ko si oloṣelu to kọja ibawi fun awọn ọmọ Naijiria ati orilẹ-ede agbaye.
Ati pe o ṣe pataki ki ijọba ati EFCC ṣe e bo ṣe tọ, dipo bi wọn ṣe ni awọn oloṣelu kan ṣe maa n lo awọn EFCC lati fi halẹ mọ awọn alatako wọn.
Ninu iwe ẹsun ti wọn kọ si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu yii ni wọn ti ni ki wọn pe Yahaya Bello ati gbogbo awọn ẹṣọ alaabo, to fi mọ awọn jankanjankan mi-in ti wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹ lẹjọ fun ẹsun ikowo ilu jẹ ati titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ.
Ninu iwe yii ni wọn ti ke si ijọba ilẹ UK, ijọba apapọ ilẹ Naijiria ati ajọ agbaye, lati gba awọn eeyan ipinlẹ Kogi nipa biba gomina tẹlẹri naa ṣẹjọ, ki wọn si gba gbogbo owo to ko jẹ lasiko to n ṣejọba.
Wọn ni awọn ko tori nnkan meji jade, bi ko ṣe ọna lati ja fun ẹtọ awọn eeyan ipinlẹ Kogi, ti wọn n jẹ iya labẹ ijọba to ṣẹṣẹ kogba wọle nipinlẹ naa.
“A n ṣe eleyii lati fi atilẹyin han si ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lori ija wọn ta ko gomina ipinlẹ Kogi, fun gbogbo iwa ibajẹ to hu si Kogi atawọn eeyan ẹ, ninu ijọba to ṣẹṣẹ pari naa”.
Ninu lẹta ti wọn kọ si Aarẹ Tinubu, lati ọwọ aṣoju ilẹ Naijiria ni UK, Ambassador Cyprian Heen. Wọn ni igbesẹ kiakia lawọn n fẹ lori ọrọ ikowojẹ ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu ti wọn n wa Bello fun, gẹgẹ bi ajọ EFCC ṣe sọ.
“Gbogbo awọn ẹsun yii, eyi lilẹdi apo pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto aabo ipinlẹ naa pẹlu ẹ, titapo si aṣọ aala ọmọluabi ipinlẹ Kogi, igbaye-gbadun awọn eeyan ẹ ati ipadanu ọpọlọpọ awọn eeyan wa”.
“Akọkọ ninu nnkan ti a fẹ ni ki wọn fi panpẹ ọba gbe Bello atawọn ẹmẹwa rẹ ni mọnawaa. A fẹ ki wọn mu gomina wa ana to n sa sabẹ gomina to wa lori ipo, eyi ti Bello fara pamọ sọdọ rẹ ni Lugard House, niluu Lọkọja.
“Ẹẹkeji ni iwadii finnifinni. A n rọ ajọ EFCC atawọn ileeṣẹ eto idajọ tọrọ kan lati ma ṣe tẹti lori iwadii to gbooro ti ko si ni kọnu-n-kọhọ ninu ti wọn n ṣe nipa ẹsun ṣiṣe owo baṣubaṣu ati iwa ọdaran yii.
“Bakan naa la tun n fẹ ki wọn fi oju Bello ba ile-ẹjọ, ki wọn si gba gbogbo ẹtọ ilu to wa ni ikawọ rẹ pada. Ti iwadii ti wọn n se yii ba le fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan gomina tẹlẹ yii, gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu ẹ la fẹ ki wọn ba ṣe ẹjọ, ki wọn si gba gbogbo owo ti wọn ko jọ tabi ti wọn ṣe arọndarọnda rẹ pada sinu asunwọn ijọba apapọ, ko le ṣanfaani fun gbogbo araalu, ki eleyii le jẹ ẹkọ fawọn to ba ṣe bẹẹ lọjọ iwaju.
“Nnkan ikẹrin ta a n fẹ ni aabo to peye faraalu atawọn aṣofofo-gbowo (whistleblowers), to fi mọ gbogbo ẹlẹrii lori ọrọ yii. Ki ijọba ri i daju pe wọn ko doju ija kọ wọn nisinyii, tabi lẹyin ti ẹjọ ba pari”.
Nigba ti wọn n rọ Aarẹ Tinubu ati ajọ EFCC lati ba wọn tete da si ọrọ naa, ki wọn ma si ṣe fi sibi kan ju ibi kan lọ, wọn kadii ọrọ wọn nipa mimu aba wa fun ijọba lati ṣeto ti yoo maa tọpinpin awọn to wa nijọba, lati le dena iru iwa aburu bẹẹ lọjọ iwaju nipinlẹ Kogi ati nibomi-in.