Niwọn igba ti ijọba ko ti mu awọn to ti leeyan kuro laduugbo wọn ṣaaju, wọn ko le mu Sunday Igboho-Falana

 Ikilọ ti lọ sọdọ awọn ọlọpaa ilẹ wa latọwọ ajafẹtọọ-ọmọniyan nni, Fẹmi Falana, pe eewọ ni fun wọn lati mu ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho, niwọn igba ti wọn ko ti le mu awọn ẹya mi-in to ti le awọn eeyan ni agbegbe wọn ṣaaju asiko yii.

Ninu ifọrwerọ kan ti ileeṣẹ iwe iroyin Punch ṣe pẹlu Falana lo ti sọrọ naa pe ‘‘Mo rọ awọn ọlọpaa ki wọn ma gbidanwo pe wọn fẹẹ mu Sunday Igboho rara, nitori ilu yii kan naa la jọ wa nigba ti awọn ẹya kan jawe ‘ẹ kuro lọdọ wa’ fun awọn ẹya mi-in ni orileede yii kan naa, ti ko si sẹni to mu wọn si i.’’

Falana fi kun un pe wọn ti le awọn alimajiri lati agbegbe kan si omi-in, wọn ti le awọn to n ṣagbe, wọn ti le awọn were atawọn eeyan ti ko da pe kuro ni awọn agbegbe kan, ijọba ko sọ nnkan kan. Ti wọn ko ba sọrọ lori eleyii, ko yẹ ki wọn waa sọ pe awọn fẹẹ mu Sunday Igboho nitori gbedeke ọjọ meje to fun awọn Fulani darandaran lati kuro ni agbegbe Ibarapa.

 Agbejọrọ yii ni asiko ti to fun agbegbe kọọkan lati ṣeto aabo fun awọn eeyan agbegbe rẹ nitori ijọba ko ṣee gbẹkẹle mọ lori eto aabo.

Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bi Gomina ipinlẹ Ọyọ ati Ondo, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ati Rotimi Akeredolu ṣe sare lọ sọdọ Aarẹ Buhari lasiko rogbodiyan naa. O ni awọn ni ọga eleto aabo fun ipinle wọn, awọn lo si yẹ ki wọn wa ọna abayọ si iṣoro to n dojukọ wọn, dipo ti wọn fi n sare kiri.

Leave a Reply