Nnkan abuku patapata ni bi wọn ṣe n ji awọn ọba alaye gbe nilẹ Yoruba- Ọba Sanni 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Onigedegede ti ilu Gedegede Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, Ọba Walidu Sanni, ti juwe bawọn Fulani ṣe n ji awọn ọba alade gbe kaakiri bii abuku ati itiju nla.

Ọba Sanni sọrọ yii lasiko to n fi ero ọkan rẹ han lori bi wọn ṣe ji awọn ọba mẹta kan gbe nipinlẹ Ekiti laipẹ yii, ati bi awọn janduku tun ṣẹṣẹ ṣe ji odidi Emir kan gbe nipinlẹ Kaduna, ẹni ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ bayii.

O ni oun gan-an ti foju wina iya latọwọ awọn Bororo ọhun ri lọjọ ti wọn waa ka oun mọ inu aafin ilu, nibi ti wọn ti lu oun lalubami, ti wọn si tun gbiyanju ati gbẹmi oun ki Ọlọrun too gba oun silẹ lọwọ wọn.

Yatọ si Ọba Sunday Daodu ti i ṣe Oniyani ti Iyani Akoko ti wọn ji gbe nitosi Ọba Akoko laipẹ yii, akaimọye orí-ade, Adele-Ọba atawọn olori lo ni wọn ti ji gbe lori ilẹ baba wọn lagbegbe Akoko nikan, to si jẹ pe wọn ko fi wọn silẹ ninu igbo ti wọn fipa gbe wọn lọ, afigba ti wọn san onitibiti owo fun awọn Fulani to ji wọn gbe.

Onigedegede ni ọrọ awọn Fulani ajinigbe ọhun ti di atẹgun to wọnu yara lọọ ka aṣọ lori itẹ, ṣe ni kẹni to wọ tirẹ sọrun tete yaa maa fura nitori pe ti wọn ba le maa ji awọn ọba alaye ti wọn duro gẹgẹ bii aworo ninu aṣa ati iṣe nilẹ Yoruba, meloo meloo ni ti awọn araalu ti wọn ti bogun awọn janduku naa lọ.

Ọba Sanni ni asiko ti to fun ijọba apapọ lati fopin si iwa abuku, itiju ati ẹgan tawọn Fulani naa n hu sawọn ori-ade lọwọlọwọ nipa siṣeto akanṣe eto aabo fun wọn.

Bakan naa lo tun rọ awọn ọba ẹlẹgbẹ rẹ lati ko awọn ọlọdẹ ibilẹ atawọn fijilante jọ lagbegbe wọn, ki wọn le fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo lati pese aabo to yẹ fawọn ọba ati araalu.

Leave a Reply