Nnkan de! Awọn ajinigbe ji Kabiyesi gbe laafin l’Ondo

Iyiade Oluṣẹyẹ, Akurẹ

Ninu ibẹru-bojo ni awọn eeyan ilu Oloso ti ilu Oso, to wa ni Ariwa Iwọ Oorun Akoko, nipinlẹ Ondo, wa bayii pẹlu bi awọn agbebọn kan ṣe ya wọnu ilu naa ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjila yii, ti wọn si ji Ọba ilu naa, Clement Jimoh Olukọtun, gbe lọ laafin ni nnkan bii aagoo mẹwaa aabọ alẹ.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn ajingbe naa yii aafin yii po lalẹ ọjọ yii. Bi wọn si ti debẹ ni wọn n sọ pe ki awọn eeyan naa ṣilẹkun lẹrọ, wọn ni ti wọn ba ti tete ṣilẹkun, ti wọn si fọwọ sọwọ pọ pẹlu awọn, awọn ko ni i ṣe wọn ni jamba, ṣugbọn awọn to wa ninu aafin yii ko dahun, ta lo fẹẹ riku ti yoo pa a ti yoo ṣilẹkun fun un.

Ibinu pe awọn eeyan naa ko da wọn lohun ni wọn fi da ibọn bolẹ, ti wọn si n yin in lakọ lakọ. Asiko naa ni awọn ajinigbe yii fi ibọn fọ gbogbo ilẹkun ẹnu ọna aafin, ti wọn si ba gbogbo ilẹkun naa jẹ.

Taara ni wọn lọ si ẹnu ọna yara ti ọba alaye naa wa, ti wọn si ibọn fọ ọ, ni wọn ba wọ Kabiyesi jade, wọn gbe e ni papanyaka, wọn si gbe e sa lọ.

Awọn mọlẹbi ọba yii atawọn eeyan ilu naa ti wọn wa nitosi lasiko iṣẹlẹ ọhun sọ pe awọn ajinigbe lo ṣiṣẹ naa, o si ṣee ṣe ki wọn ti maa ṣọ ọba alaye yii, tabi ki wọn ni ẹni kan to n ṣe ami fun wọn niluu naa.

A gbọ pe wọn ko ti i kan si awọn mọlẹbi lati sọ fun wọn pe ọdọ awọn ni Kabiyesi wa, tabi lati sọ pe iye bayii laọn fẹẹ gba. Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, to fidi ọrọ yii mulẹ sọ pe awọn ko ti i ni iroyin to to lori iṣẹlẹ naa. O ni awọn ọlọpaa Oke-Agbe ti ko awọn ọmọọṣẹ wọn da sita lati ṣawari ọba alaye yii.

Leave a Reply