Nnkan de! Sunday ti wọn mu pe o n pa awọn eeyan l’Akinyẹle ti sa lọ lagọọ ọlọpaa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Iroyin ibanujẹ gbaa lo jẹ fawọn olugbe ijọba ibilẹ Akinyẹle, awọn olugbe Ibadan ati gbogbo ara ipinlẹ Ọyọ lapapọ nigba ti oỌga agba olọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, fidi ẹ mulẹ pe Sunday Shodipẹ, afurasi ọdaran to n pa kukuru, pa gigun kaakiri agbegbe Akinyẹle, n’Ibadan, ti sa jade latimọle awọn.

Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ yii, SP Olugbenga Fadeyi, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ọga agba ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe loootọ lọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun (19) to ti paayan bii mẹwaa laarin oṣu kan aabọ ọhun ti sa mọ awọn lọwọ ninu atimọle ti awọn fi i pamọ si.

Lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja, ni wọn lọmọkunrin naa sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ ninu ahamọ ti wọn fi i si lẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran laduugbo Iyaganku, n’Ibadan.

Gẹgẹ bi SP Olugbenga ṣe kọ ọ sinu atẹjade ọhun, “ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi asiko yii kede pe ọga awọn afurasi ọdaran to n pa awọn eeyan kiri l’Akinyẹle, ẹni ta a ṣafihan  oun pẹlu awọn afurasi ọdaran ẹgbẹ ẹ meji mi-in papọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje, ọdun 2020 yii, ti sa kuro ninu ahamọ lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun yii, lẹyin ta a ti gbe e lọ si kootu, tile-ẹjọ si ti paṣẹ pe ka fi i pamọ sinu ahamọ wa.

“Nitori idi eyi, a rọ ẹyin eeyan lati ba wa foju léde, kẹ́ ẹ le mu ọmọkunrin naa nibikibi tẹ ẹ ba ti ri i, kẹ ẹ si fa a le awọn agbofinro lọwọ ni teṣan ọlọpaa to ba sun mọ yin ju lọ, ka le gbe igbesẹ to ba yẹ lori ẹ.”

Bakan naa ni CP Enwonwu rọ ẹnikẹni to ba ni iroyin to le ran awọn agbofinro lọwọ lori bi wọn ṣe le ri afurasi ọdaran naa mu pada, lati tete ta awọn ọlọpaa lolobo nipa ẹ.

3 thoughts on “Nnkan de! Sunday ti wọn mu pe o n pa awọn eeyan l’Akinyẹle ti sa lọ lagọọ ọlọpaa n’Ibadan

  1. Eleyi tungbenutan o Awon Olopa towani ibi ise nijono nko ha eleyi kose gbo seti o abuku patapata loje fun Awon Olopa ki won wadi lodo Awon ti oye komaso Apaniyon no

  2. Iro lasan ni won pa fun ara won eo ri wipe nkan ti baje mo eto abo wa lorileede yi lara to fi je pe ifokanbale kan o si laye yi mo se eyin o mope awon oga ti pe latoke pe ki won fi Sunday sile pe omo awon ni, sugbon eni to n sere ko ma sere eniyan to n seka ko ma seka atore atika nkan o ni gbe

Leave a Reply