Nnkan de! Wọn ji Biṣọọbu atiyawo ẹ gbe pẹlu awakọ wọn lọna Ogbomọṣọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu aibalẹ ọkan ni gbogbo ijọ Anglican nilẹ yii wa bayii, bẹẹ lọkan ọpọ eeyan nilẹ Yoruba ko fi ibalẹ-ọkan rinrin ajo pẹlu bi awọn ajinigbe ṣe ji olori ijọ naa atiyawo ẹ gbe pẹlu awakọ wọn lori irin-ajo.
Ẹni-ọwọ agba Aderọgba, to jẹ biṣọọbu ijọ Anglican fun gbogbo ẹkun Jẹbba nipinlẹ Kogi, ati iyawo ẹ pẹlu awakọ wọn lawọn ọbayejẹ ẹda kan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ji gbe nigba ti wọn n ti ilu Jẹbba lọ si Yewa, nipinlẹ Ogun.

Bo tilẹ jẹ pe awọn iranṣẹ eṣu ọdaran yii ko ti i pe awọn mọlẹbi Biṣọọbu naa lati sọ nnkan ti wọn n fẹ gan-an lọwọ wọn, iriri gbogbo ọmọ orileede yii lati nnkan bii asiko diẹ sẹyin, fi han pe awọn ajinigbe lo da wọn lọna loju ọna tuntun to so Ogbomọṣọ ati ilu Ọyọ pọ, ti wọn si fi ibọn sin wọn wọnu igbo lọ ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ Aiku, iyẹn Sannde, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, ti wọn si ji wọn gbe.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni loju-ẹsẹ ti wọn ti fi iṣẹlẹ yii to awọn leti lawọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lati ri awọn eeyan Ọlọrun naa tu silẹ nigbekun awọn ajinigbe.
O ni, “Iwadii fi ye wa pe lasiko ti ọkọ awọn Biṣọọbu yẹn bajẹ loju ọna lawọn afurasi ajinigbe naa yọ si wọn lojiji, ti wọn si ji wọn gbe.

“Igbakeji ọga agba ọlọpaa ipinlẹ yii to jẹ alamoojuto iṣẹ agbofinro lo ko ọpọlọpọ igbimọ oluwadii lẹnu iṣẹ ọlọpaa lẹyin lati le ri awọn eeyan naa gba silẹ laaye ati lai fara pa.

“Lara awọn ikọ to n sa gbogbo agbara wọn lati wa awọn eeyan naa kan, ki wọn si gba wọn silẹ, ni ikọ awọn agbofinro to n gbogun ti ijinigbe, ikọ ayọkẹlẹpẹkun, awọn adigboluja, awọn to n koju iṣẹlẹ igbesunmọni ati bẹẹ bẹẹ lọ.’’

O waa fi ọkan awọn araalu balẹ lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya, o ni awọn agbofinro ti gbakoso eto aabo layiika wọn gbogbo.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: