Nnkan de! Wọn ti tun mu oṣere tiata mi-in fẹsun ifipa-ba-ni-lo-pọ

Faith Adebọla

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ti ba afurasi ọdaran kan to jẹ ọkan ninu awọn onitiata to ṣẹṣẹ n goke agba bọ nilẹ wa, Ọgbẹni Praise. Ẹsun ti wọn fi kan gende ẹni ọgbọn ọdun ọhun ni pe o fipa ba ọmọdebinrin ọmọọdun mẹrinla kan laṣepọ, o si ṣ’ọmọ ọhun yankan-yankan.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, to sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede soju opo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lori ẹrọ ayelujara ni l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un ta a wa yii, niṣẹlẹ naa waye, nigba ti awọn ọmọleewe wa ninu ọlide ayajọ awọn oṣiṣẹ. Ọjọ naa lawọn obi ọdọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun kegbajare wa si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Mowe, wọn lawọn n wa ọmọọmọ awọn, lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii lo ti jade nile, bii pe o n ṣere laduugbo lawọn kọkọ pe e, afi bo ṣe di imi ọkẹrẹ, ti wọn wa a titi, ti wọn ko si ri i, wọn o si mọ’bi to wọlẹ si.

Amọ lẹyin ọpọlọpọ idaamu ati isapa, wọn lawọn papa ri ọmọbinrin naa, o jẹwọ pe Praise lo mu oun sọdọ, niṣe lo ji oun gbe, to si bẹrẹ si i dana ibalopọ soun labẹ, nigba ti wọn si yẹ abẹ ọmọ ọhun wo, wọn ri i pe o ti degbo, ẹjẹ si n jade loju ara rẹ.

Lọgan lawọn ọlọpaa ti tọpasẹ afurasi ọdaran yii lọ, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e.

Bakan naa ni wọn ṣeto lati gbe ọmọbinrin to kagbako ibasun ọran yii lọ sileewosan ijọba fun ayẹwo ati itọju to peye.

Ṣa, wọn ti taari afurasi yii si akata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, to wa l’Eleweẹran, fun iwadii to rinlẹ.

Odutọla ni awọn ko ni i gba kẹnikẹni foju ọmọde rare tabi ṣe wọn baṣubaṣu, wọn lawọn maa wọ Praise dewaju adajọ tiwadii ba ti pari.

Ẹ oo ranti pe ni nnkan bii ọdun meji sẹyin ni wọn fẹsun kan ilumọ-ọn-kan oṣere tiata ilẹ wa ati adẹrin-in poṣonu nni, James Ọlanrewaju, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, fun iru ẹsun yii. Abare-babọ ẹsun ati igbẹjọ, ile-ẹjọ paṣẹ ki wọn ju ọkunrin naa sẹwọn ọdun mẹrindinlogun, wọn lo jẹbi ṣiṣe ere egele pẹlu ọmọdebinrin ọmọọdun mẹrinla kan.

Amọ ṣa o, Baba Ijẹṣa ti pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, igbẹjọ si ti n lọ lọwọ.

Leave a Reply