Nnkan itiju gbaa ni b’awọn agbebọn ṣe kọ lu ileewe awọn ologun ilẹ wa-Oyinlọla

Pẹlu bawọn agbebọn ṣe kọ lu ileewe ẹkọ awọn ologun lorilẹ-ede yii lọjọ Iṣẹgun, ti wọn pa ṣọja meji, ti wọn gbe ẹni kẹta sa lọ, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, ti ṣapejuwe ikọlu naa gẹgẹ bii nnkan itiju gbaa, eyi to ni o ti ni loju ju ole jija lọ.

Baba to ti figba kan ṣe alakooso ilu Eko ri laye ijọba ṣọja naa sọ pe bawọn janduku ba le wọ ileewe ẹkọ nipa iṣẹ ogun ni Naijiria (Nigeria Defence Academy) to wa ni Kaduna, ti wọn si pa iru itu buruku bayii, a jẹ pe ko si nnkan kan fun orilẹ-ede yii mọ nipa aabo, afi ki kaluku yaa maa gbadura k’Ọlọrun ṣọ ọ.

Oyinlọla to fi ijọniloju ati ibanujẹ sọrọ yii lori eto redio kan l’Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, sọ pe loootọ loun ko ti i gbọ hulẹhulẹ iṣẹlẹ naa, ṣugbọn sibẹ naa, nnkan abuku gbaa lo ṣẹlẹ si Naijiria yii, o si daju pe ẹnikan ti fi iṣẹ rẹ silẹ lai ṣe lomi fi tẹyin wọgbin lẹnu.

Ohun to tilẹ tun mu ọrọ naa dun Oyinlọla gẹgẹ bo ṣe wi ni pe ṣọja loun naa tẹlẹ. O ni ọgbọn ọdun gbako loun fi ṣe ṣọja, ṣe iṣẹ ṣọja naa lo ti waa winlẹ to bẹẹ, to fi di ohun ti awọn kan n ya bo ibi to yẹ ko jẹ ile agbara awọn ṣọja fun gbogbo orilẹ-ede yii.

Nigba to n dahun ibeere pe ṣe loootọ lo fẹẹ dupo alaga PDP lapapọ, Oyinlọla sọ pe afi ti wọn ba gbe e wa si ilẹ Yoruba, boun ba si le ri atilẹyin awọn alẹnulọrọ ni.

Leave a Reply